Esek 21:1-31

Esek 21:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe. Ọmọ enia, kọju rẹ sihà Jerusalemu, si sọ ọ̀rọ si ibi mimọ́ wọnni, si sọtẹlẹ si ilẹ Israeli. Si wi fun ilẹ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ ọ, emi o si fa idà mi yọ kuro li akọ̀ rẹ̀, emi o si ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ. Njẹ bi o ti ṣe pe emi o ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ, nitorina ni idà mi o ṣe jade lọ lati inu àkọ rẹ̀, si gbogbo ẹran-ara, lati gusù de ariwa: Ki gbogbo ẹran-ara le mọ̀ pe emi Oluwa ti fà idà mi yọ kuro li àkọ rẹ̀: kì yio pada mọ lai. Nitorina kerora, iwọ ọmọ enia, pẹlu ṣiṣẹ́ ẹgbẹ́ rẹ, ati pẹlu ikerora kikoro niwaju wọn. Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkerora? iwọ o dahùn wipe, Nitori ihìn na; nitoripe o de: olukuluku ọkàn ni yio yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yio si ṣe ailokun, olukuluku ẹmi yio si dakú, gbogbo ẽkún ni yio ṣe ailagbara bi omi: kiyesi i, o de, a o si mu u ṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi li Oluwa wi; Wipe, Idà, idà ti a pọ́n, ti a si dán pẹlu: A pọ́n ọ lati pa enia pupọ; a dán a lati ma kọ màna: awa o ha ma ṣe ariyá? ọgọ ọmọ mi, o gàn gbogbo igi. On si ti fi i le ni lọwọ lati dán, ki a ba le lò o; idà yi li a pọ́n, ti a si dán, lati fi i le ọwọ́ apani. Kigbe, ki o si wu, ọmọ enia: nitori yio wá sori awọn enia mi, yio wá sori gbogbo ọmọ-alade Israeli: ìbẹru nla yio wá sori awọn enia mi nitori idà na: nitorina lu itan rẹ. Nitoripe idanwo ni, ki si ni bi idà na gàn ọgọ na? kì yio si mọ́, ni Oluwa Ọlọrun wi. Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ, si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, si jẹ ki idà ki o ṣẹ́po nigba kẹta, idà awọn ti a pa: idà awọn enia nla ti a pa ni, ti o wọ inu yara ikọ̀kọ wọn lọ. Mo ti nà ṣonṣo idà si gbogbo bode wọn: ki aiya wọn le dakú, ati ki ahoro wọn le di pupọ: ã! a ti ṣe e dán, a ti pọ́n ọ mú silẹ fun pipa. Iwọ gba ọ̀na kan tabi ọ̀na keji lọ, si apa ọtún tabi si òsi, nibikibi ti iwọ dojukọ. Emi o si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, emi o si jẹ ki irúnu mi ki o simi: emi Oluwa li o ti wi bẹ̃. Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ pẹlu, ọmọ enia, yan ọ̀na meji fun ara rẹ, ki idà ọba Babiloni ki o le wá: awọn mejeji yio jade lati ilẹ kanna wá: si yan ibi kan, yàn a ni ikorita ti o lọ si ilu-nla. Yàn ọ̀na kan, ki idà na le wá si Rabba ti awọn ara Ammoni, ati si Juda ni Jerusalemu ti o li odi. Nitori ọba Babiloni duro ni iyàna, lori ọ̀na meji, lati ma lo afọṣẹ: o mì ọfà rẹ̀, o da òriṣa, o wo ẹ̀dọ. Li ọwọ́ ọtún rẹ̀ ni afọṣẹ Jerusalemu wà, lati yan õlù, lati ya ẹnu rẹ̀ ni pipa, lati gbohùn soke pẹlu ariwo, lati yan õlù si bode, lati mọ odi, ati lati kọ ile iṣọ́. Afọ̀ṣẹ na yio si dabi eké fun wọn, loju awọn ti o ti bura fun wọn: ṣugbọn on o mu aiṣedẽde wá si iranti, ki a ba le mu wọn. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe ẹnyin jẹ ki a ranti aiṣedẽde nyin, niti pe a ri irekọja nyin, tobẹ̃ ti ẹ̀ṣẹ nyin hàn, ni gbogbo iṣe nyin: nitoripe ẹnyin wá si iranti, ọwọ́ li a o fi mu nyin. Ati iwọ, alailọ̀wọ ẹni-buburu ọmọ-alade Israeli, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedẽde ikẹhìn. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Mu fila ọba kuro, si ṣi ade kuro; eyi kò ni jẹ ọkanna: gbe ẹniti o rẹlẹ ga, si rẹ̀ ẹniti o ga silẹ. Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì i subu, kì yio si si mọ, titi igbati ẹniti o ni i ba de; emi o si fi fun u. Ati iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti awọn ara Ammoni, ati niti ẹgàn wọn; ani ki iwọ wipe, Idà na, idà na ti a fà yọ, a ti dán a fun pipa, lati parun lati kọ màna. Nigbati nwọn ri ohun asan si ọ, nigbati nwọn fọ̀ àfọṣẹ eke si ọ, lati mu ọ wá si ọrùn awọn ti a pa, ti ẹni-buburu, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigbati aiṣedẽde pin. Tun mu ki o pada sinu àkọ rẹ̀! Emi o ṣe idajọ rẹ nibi ti a gbe ṣe ẹdá rẹ, ni ilẹ ibi rẹ. Emi o dà ibinujẹ mi le ọ lori, ninu iná irúnu mi li emi o fẹ si ọ, emi o si fi ọ le awọn eniakenia lọwọ, ti nwọn ni ọgbọn lati parun.

Esek 21:1-31 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú. N óo pa àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú tí ó wà ninu rẹ run, nítorí náà, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo eniyan láti ìhà gúsù títí dé ìhà àríwá. Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo fa idà mi yọ, n kò sì ní dá a pada sinu àkọ̀ mọ́.’ “Ìwọ ọmọ eniyan, máa mí ìmí ẹ̀dùn, bí ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dàrú, tí ó sì ń kẹ́dùn níwájú wọn. Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé èmi: OLUWA Ọlọrun ní: Ẹ wo idà, àní idà tí a ti pọ́n, tí a sì ti fi epo pa. A ti pọ́n ọn láti fi paniyan; a ti fi epo pa á, kí ó lè máa kọ mànà bíi mànàmáná. Ọ̀rọ̀ yìí kìí ṣe ọ̀rọ̀ àríyá; nítorí àwọn eniyan mi kọ̀, wọn kò náání ìkìlọ̀ ati ìbáwí mi. Nítorí náà, a pọ́n idà náà, a sì fi epo pa á, kí á lè fi lé ẹni tí yóo fi paniyan lọ́wọ́. Ìwọ ọmọ eniyan, kígbe, kí o sì pohùnréré ẹkún, nítorí àwọn eniyan mi ni a yọ idà sí; ati àwọn olórí ní Israẹli. Gbogbo wọn ni a óo fi idà pa pẹlu àwọn eniyan mi. Nítorí náà káwọ́ lérí kí o sì máa hu. Mò ń dán àwọn eniyan mi wò, bí wọ́n bá sì kọ̀, tí wọn kò ronupiwada, gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn, Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sápẹ́, fi idà lalẹ̀ léraléra, idà tí a fà yọ tí a fẹ́ fi paniyan. Idà tí yóo pa ọ̀pọ̀ eniyan ní ìpakúpa, tí ó sì súnmọ́ tòsí wọn pẹ́kípẹ́kí. Kí àyà wọn lè já, kí ọpọlọpọ lè kú ní ẹnubodè wọn. Mo ti fi idà tí ń dán lélẹ̀ fún pípa eniyan, ó ń kọ mànà bíi mànàmáná, a sì ti fi epo pa á. Máa pa wọ́n lọ ní ọwọ́ ọ̀tún, ati ní ọwọ́ òsì, níbikíbi tí ó bá sá ti kọjú sí. Èmi náà yóo máa pàtẹ́wọ́, inú tí ń bí mi yóo sì rọ̀, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, la ọ̀nà meji fún idà ọba Babiloni láti gbà wọ̀lú, kí ọ̀nà mejeeji wá láti ilẹ̀ kan náà. Fi atọ́ka sí oríta níbi tí ọ̀nà ti yà wọ ìlú. La ọ̀nà fún idà kan láti gbà wọ ìlú Raba ní ilẹ̀ Amoni, kí o sì la ọ̀nà mìíràn fún idà láti gbà wọ ilẹ̀ Juda ati ìlú Jerusalẹmu tí a mọ odi yíká. Nítorí pé ọba Babiloni ti dúró sí oríta, ní ibi tí ọ̀nà ti pínyà; ó dúró láti ṣe àyẹ̀wò. Ó mi ọfà, ó bá oriṣa sọ̀rọ̀, ó sì woṣẹ́ lára ẹ̀dọ̀ ẹran. Ọfà ìbò Jerusalẹmu yóo bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Yóo kígbe, àwọn eniyan náà yóo sì kígbe sókè. Wọn óo gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ìlẹ̀kùn ti ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀, wọn yóo mọ òkítì sí ara odi rẹ̀, wọn yóo sì mọ ilé ìṣọ́ tì í. Gbogbo ohun tí ó ń ṣe yóo dàbí ẹni tí ń dífá irọ́ lójú àwọn ará ìlú, nítorí pé majẹmu tí wọ́n ti dá yóo ti kì wọ́n láyà; ṣugbọn ọba Babiloni yóo mú wọn ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, yóo ṣẹgun wọn yóo sì kó wọn lọ. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ní, ẹ ti jẹ́ kí n ranti ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí pé ẹ ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín, ninu gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ yín ti hàn; ogun yóo ko yín nítorí pé ẹ ti mú kí n ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. “Ìwọ olórí Israẹli, aláìmọ́ ati ẹni ibi, ọjọ́ rẹ pé; àkókò ìjìyà ìkẹyìn rẹ sì ti tó. Ẹ ṣí fìlà, kí ẹ sì ṣí adé ọba kúrò lórí, gbogbo nǹkan kò ní wà bí wọ́n ṣe rí. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ẹ gbé àwọn tí ipò wọn rẹlẹ̀ ga, kí ẹ sì rẹ àwọn tí ipò wọn wà lókè sílẹ̀. Ìparun! Ìparun! N óo pa ìlú yìí run ni; ṣugbọn n kò ní tíì pa á run, títí ẹni tí ó ni í yóo fi dé, tí n óo sì fi lé e lọ́wọ́. “Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Amoni ati ẹ̀gàn wọn nìyí: ‘A ti fa idà yọ, láti paniyan. A ti fi epo pa á kí ó lè máa dán, kí ó sì máa kọ mànà bíi mànàmáná. Nígbà tí wọn ń ríran èké, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́ fún ọ, a óo gbé idà náà lé ọrùn àwọn aláìmọ́ ati ẹni ibi, tí ọjọ́ wọn ti pé, àní ọjọ́ ìjìyà ìkẹyìn wọn. “ ‘Dá idà náà pada sinu àkọ̀ rẹ̀. Ní ilẹ̀ rẹ ní ibi tí a ti dá ọ, ni n óo ti dá ọ lẹ́jọ́. N óo bínú sí ọ lọpọlọpọ, ìrúnú mi yóo jó ọ bí iná, n óo fà ọ́ lé àwọn oníjàgídíjàgan lọ́wọ́, àwọn tí wọ́n mọ̀ bí wọ́n ṣe ń panirun.

Esek 21:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ mi wá: “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli. Kí ó sì sọ fún un pe: ‘Èyí yìí ni OLúWA wí: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín. Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá. Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi OLúWA ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’ “Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni OLúWA Olódùmarè wí.” Ọ̀rọ̀ OLúWA si tún tọ̀ mí wá pé: “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí pé: “ ‘Idà kan, Idà kan, tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú, a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀. “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbámú; a pọ́n ọn, a sì dán an, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani. Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi; yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà; nítorí náà lu oókan àyà rẹ. “ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ńkọ́? Ni OLúWA Olódùmarè wí.’ “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ Tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún. Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun. Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀ Èmi OLúWA ti sọ̀rọ̀.” Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ mi wá: “Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe ààmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà. La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi. Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀. Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́. Àfọ̀ṣẹ náà yóò dàbí ààmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn. “Nítorí náà èyí ní ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn. “ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó, Èyí yìí ní ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀, Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’ “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí OLúWA Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a ó pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó. “ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀ Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà.