Esek 20:1-49
Esek 20:1-49 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe ni ọdun keje ni oṣu karun, ni ọjọ kẹwa oṣu, ti awọn kan ninu awọn àgba Israeli wá ibere lọwọ Oluwa, nwọn si joko niwaju mi. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere. Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn. Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ. Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin. Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti. Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi; ki o má bà bajẹ niwaju awọn keferi, lãrin ẹniti nwọn wà, loju ẹniti mo sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn, ni mimu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti. Mo si jẹ ki wọn lọ kuro ni ilẹ Egipti, mo si mu wọn wá si aginju. Mo si fi aṣẹ mi fun wọn, mo si fi idajọ mi hàn wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn. Pẹlupẹlu mo si fun wọn ni ọjọ isimi mi, lati ṣe àmi lãrin t'emi ti wọn, ki nwọn ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa ti o yà wọn si mimọ́. Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run. Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má ba di ibajẹ niwaju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade. Pẹlupẹlu mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn ni aginju pe emi kò ni mu wọn de ilẹ ti mo ti fi fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ; Nitoriti nwọn gàn idajọ mi, nwọn kò si rìn ninu aṣẹ mi, ṣugbọn nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: nitoripe ọkàn wọn tẹ̀le oriṣa wọn. Ṣugbọn oju mi dá wọn si ki emi má ba pa wọn, bẹ̃ni emi kò ṣe wọn li aṣetan ni aginju. Ṣugbọn mo sọ fun awọn ọmọ wọn li aginju pe, Ẹ máṣe rìn ninu aṣẹ baba nyin, ẹ má si ṣe kiyesi idajọ wọn, ẹ má si fi oriṣa wọn sọ ara nyin di aimọ́: Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: ẹ rìn ninu aṣẹ mi, ẹ si pa idajọ mi mọ, ẹ si ṣe wọn; Ẹ si bọ̀wọ fun ọjọ isimi mi; nwọn o si jẹ àmi lãrin t'emi ti nyin, ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa Ọlọrun nyin. Ṣugbọn awọn ọmọ na ṣọ̀tẹ si mi: nwọn kò rìn ninu aṣẹ mi, bẹ̃ni nwọn kò pa idajọ mi mọ lati ṣe wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn; nwọn bà ọjọ isimi mi jẹ: mo si wipe, Emi o da irúnu mi sori wọn, lati pari ibinu mi sori wọn li aginju. Ṣugbọn mo fà ọwọ́ mi sẹhìn, mo si ṣiṣẹ nitori orukọ mi, ki o má bà di ibajẹ li oju awọn keferi, loju ẹniti mo mu wọn jade. Mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn pẹlu li aginju, lati tú wọn ka lãrin awọn keferi, ati lati fọ́n wọn ká ilẹ gbogbo; Nitoripe nwọn kò mu idajọ mi ṣẹ, ṣugbọn nwọn kẹgàn aṣẹ mi, nwọn si ti bà ọjọ isimi mi jẹ, oju wọn si wà lara oriṣa baba wọn. Nitorina mo fun wọn ni aṣẹ pẹlu ti kò dara, ati idajọ nipa eyiti wọn kì yio fi le yè; Emi si bà wọn jẹ́ ninu ẹ̀bun ara wọn, nitipe nwọn mu gbogbo awọn akọbi kọja lãrin iná, ki emi ba le sọ wọn di ahoro, ki nwọn le bà mọ̀ pe emi ni Oluwa. Nitorina, ọmọ enia, sọ fun ile Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ninu eyi pẹlu baba nyin ti sọ̀rọ odi si mi, nitipe nwọn ti dẹṣẹ si mi. Nitori nigbati mo ti mu wọn de ilẹ, niti eyiti mo gbé ọwọ́ mi soke lati fi i fun wọn, nigbana ni nwọn ri olukuluku oke giga, ati gbogbo igi bibò, nwọn si ru ẹbọ wọn nibẹ, nwọn si gbe imunibinu ọrẹ wọn kalẹ nibẹ: nibẹ pẹlu ni nwọn ṣe õrun didùn wọn, nwọn si ta ohun-ọrẹ mimu silẹ nibẹ. Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Kini ibi giga ti ẹnyin nlọ na? Orukọ rẹ̀ ni a si npe ni Bama titi o fi di oni oloni. Si wi fun ile Israeli pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; A bà nyin jẹ́ gẹgẹ bi baba nyin? ẹnyin si ṣe agbère gẹgẹ bi ohun-irira wọn? Nitori nigbati ẹnyin nta ọrẹ nyin, nigbati ẹnyin mu ọmọ nyin kọja lãrin iná, ẹnyin fi oriṣa nyin bà ara nyin jẹ́, ani titi o fi di oni oloni: ẹnyin o ha si bere lọwọ mi, Iwọ ile Israeli? Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere. Eyiti o si wá si iye nyin kì yio wà rara; ti ẹnyin wipe, Awa o wà bi awọn keferi, gẹgẹ bi idile awọn orilẹ-ède lati bọ igi ati okuta. Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ nipa agbara ọwọ́, ati ninà apa, pẹlu irúnu ti a dà jade li emi o fi jọba lori nyin: Emi o si mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, emi o si ṣà nyin jọ lati ilẹ ti a ti tú nyin ka si, pẹlu ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ati pẹlu irúnu ti a dà jade. Emi o si mu nyin wá si aginju awọn enia, nibẹ ni emi o si bá nyin rojọ lojukoju. Gẹgẹ bi mo ti dá awọn baba nyin lẹjọ li aginju ilẹ Egipti, bẹ̃ni emi o bá nyin rojọ, ni Oluwa Ọlọrun wi. Emi o si mu nyin kọja labẹ ọpá, emi o si mu nyin wá si ìde majẹmu: Emi o si ṣà awọn ọlọ̀tẹ kuro lãrin nyin, ati awọn olurekọja, emi o mu wọn jade kuro ni ilẹ ti wọn gbe ṣe atipo, nwọn kì yio si wọ ilẹ Israeli: ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa. Bi o ṣe ti nyin, ile Israeli, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi, Ẹ lọ, olukuluku sìn oriṣa rẹ̀, ati lẹhin eyi pẹlu, bi ẹnyin kì yio ba fi eti si mi: ṣugbọn ẹ máṣe fi ẹ̀bun nyin ati oriṣa nyin bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ mọ. Nitori lori oke mimọ́ mi, lori oke giga Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi, nibẹ ni gbogbo ile Israeli, gbogbo wọn ni ilẹ na, yio sìn mi: nibẹ ni emi o gbà wọn, nibẹ ni emi o si bere ẹbọ nyin, ati ọrẹ akọso nyin, pẹlu ohun mimọ́ nyin. Emi o gbà nyin pẹlu õrùn didùn nyin, nigbati mo mu nyin jade kuro lãrin awọn enia, ti mo si ko nyin jọ lati ilẹ gbogbo nibiti a gbe ti tú nyin ká si; a o si yà mi si mimọ́ ninu nyin niwaju awọn keferi. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi o mu nyin de ilẹ Israeli, si ilẹ niti eyiti o gbe ọwọ́ mi soke lati fi fun awọn baba nyin. Nibẹ li ẹnyin o ranti ọ̀na nyin, ati gbogbo iṣe nyin, ninu eyiti a ti bà nyin jẹ; ẹ o si sú ara nyin loju ara nyin nitori gbogbo buburu ti ẹnyin ti ṣe. Ẹnyin o si mọ̀ pe emi ni Oluwa, nigbati emi ti ṣiṣẹ pẹlu nyin nitori orukọ mi, ki iṣe gẹgẹ bi ọ̀na buburu nyin, tabi gẹgẹ bi iṣe bibajẹ nyin, ẹnyin ile Israeli, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, kọju rẹ siha gusù, si sọ ọ̀rọ rẹ siha gusù, si sọtẹlẹ si igbó oko gusù; Si wi fun igbó gusù pe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa; bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o da iná kan ninu rẹ, yio si jo olukuluku igi tutù ninu rẹ, ati olukuluku igi gbigbẹ: jijo ọwọ́ iná na ni a kì yio pa, ati gbogbo oju lati gusu de ariwa ni a o sun ninu rẹ̀. Gbogbo ẹran-ara ni yio si ri i pe emi Oluwa li o ti da a, a kì yio pa a. Nigbana ni mo wipe, A! Oluwa Ọlọrun, nwọn wi niti emi pe, Owe ki o npa yi?
Esek 20:1-49 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ “Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe. Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé. Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀. “Nítorí náà, mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wá sinu aṣálẹ̀. Mo fún wọn ní òfin mi, mo sì fi ìlànà mi hàn wọ́n, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. Nítorí náà, mo búra fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n kò ní mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí pé n óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jù ní gbogbo ilẹ̀ ayé. Nítorí pé wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọn kò tẹ̀lé òfin mi, wọ́n sì ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, nítorí pé ọkàn wọn kò kúrò lọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn. “Sibẹsibẹ mo fojú àánú wò wọ́n, n kò pa wọ́n run sinu aṣálẹ̀. Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀ pé kí wọ́n má tọ ọ̀nà tí àwọn baba wọn rìn, kí wọ́n má ṣe tẹ̀lé òfin wọn, tabi kí wọ́n bọ oriṣa wọn. Mo ní èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. Ẹ máa rìn ní ọ̀nà mi, kí ẹ sì máa pa òfin mi mọ́. Ẹ máa pa àwọn ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí wọ́n lè jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín. “Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀. Ṣugbọn mo rowọ́, mo sì ro ti orúkọ mi, tí n kò fẹ́ kí wọ́n bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ti kó wọn jáde. Nítorí náà, mo ṣe ìlérí fún wọn ninu aṣálẹ̀ pé n óo fọ́n wọn káàkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ ìlànà mi sílẹ̀, wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́, wọn kò sì mójú kúrò lára àwọn oriṣa tí àwọn baba wọn ń bọ. “Nítorí náà, mo fún wọn ní àṣẹ tí kò dára ati ìlànà tí kò lè gbà wọ́n là. Mo jẹ́ kí ẹbọ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́, mọ jẹ́ kí wọ́n máa sun àkọ́bí wọn ninu iná, kí ìpayà lè bá wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní Ọ̀nà mìíràn tí àwọn baba yín tún fi bà mí lórúkọ jẹ́ ni pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra pé n óo fún wọn, bí wọ́n bá ti rí òkè kan tí ó ga, tabi tí wọ́n rí igi kan tí ewé rẹ̀ pọ̀, wọn a bẹ̀rẹ̀ sí gbé ẹbọ wọn kalẹ̀ sibẹ. Wọn a rú ẹbọ ìríra, wọn a mú kí òórùn dídùn ẹbọ wọn bo gbogbo ibẹ̀, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ohun mímu sílẹ̀. Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn? Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi. Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta. “Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín. N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu. N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju. Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo mú kí ẹ gba abẹ́ ọ̀pá mi kọjá, n óo sì mu yín wá sí abẹ́ ìdè majẹmu. N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.” Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA Ọlọrun ní, “Kí olukuluku yín lọ máa bọ oriṣa rẹ̀ láti ìsinsìnyìí lọ, bí ẹ kò bá fẹ́ gbọ́ tèmi, ṣugbọn ẹ kò ní fi ẹbọ ati oriṣa yín ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́. Lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni gbogbo ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli yóo ti máa sìn mí. Gbogbo yín pátá ní ilẹ̀ náà, ni ẹ óo máa sìn mí níbẹ̀. N óo yọ́nú si yín. N óo sì bèèrè ọrẹ àdájọ lọ́wọ́ yín ati ọrẹ àtinúwá tí ó dára jùlọ pẹlu ẹbọ mímọ́ yín. N óo yọ́nú si yín bí ìgbà tí mo bá gbọ́ òórùn ẹbọ dídùn, nígbà tí mo bá ń ko yín jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mò ń ko yín jọ kúrò láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè tí ẹ fọ́nká sí. Ẹwà mímọ́ mi yóo sì hàn lára yín lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ko yín dé ilẹ̀ Israẹli, ilẹ̀ tí mo búra láti fún àwọn baba ńlá yín. Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, ẹ óo ranti ìṣe yín, ati gbogbo ìwà èérí tí ẹ hù tí ẹ fi ba ara yín jẹ́. Ojú ara yín yóo sì tì yín nígbà tí ẹ bá ranti gbogbo nǹkan burúkú tí ẹ ti ṣe. Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ba yín wí nítorí orúkọ mi, tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà burúkú yín tabi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà burúkú yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí ìhà gúsù, fi iwaasu bá ìhà ibẹ̀ wí, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ilẹ̀ igbó Nẹgẹbu. Sọ fún igbó ibẹ̀ pé èmi OLUWA Ọlọrun ní n óo sọ iná sí i, yóo sì jó gbogbo àwọn igi inú rẹ̀, ati tútù ati gbígbẹ, iná náà kò ní kú. Yóo jó gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní gúsù títí dé àríwá. Gbogbo eniyan ni yóo rí i pé èmi OLUWA ni mo dá iná náà, kò sì ní ṣe é pa.” Mo bá dáhùn pé, “Áà! OLUWA Ọlọrun, wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ǹjẹ́ òun fúnrarẹ̀ kọ́ ni ó ń ro òwe yìí, tí ó sì ń pa á mọ́ wa?’ ”
Esek 20:1-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá wádìí lọ́wọ́ OLúWA, wọn jókòó níwájú mi. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní OLúWA Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’ “Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú, kí ó sì sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.” Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.” “ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti. Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù. Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ààmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni OLúWA tó sọ wọn di mímọ́. “ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní mú kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí mo kó wọn jáde. Nítorí náà, mo tún gbọ́wọ́ mi sókè ní ìbúra fún wọn nínú aginjù pé, èmi kì yóò mú wọn dé ilẹ̀ tí mo fi fún wọn—ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú aginjù. Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín, ẹ má ṣe pa òfin wọn mọ́, ẹ má ṣe bá ara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́. Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ ààmì láàrín wa: ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní OLúWA Ọlọ́run yín.” “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mi mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú mi lórí wọn, Èmi yóò sì mú kí ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni aginjù. Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nítorí orúkọ mi, mo sì ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ́ ti mo gbé sókè sí wọn, mo búra fún wọn nínú aginjù pé èmi yóò tú wọn ka sì àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo, nítorí pé wọn kò pa òfin mi mọ́, wọn sì tún kọ àṣẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ojú wọn sì wà ní ara òrìṣà baba wọn. Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀; Mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn nípa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun, àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí èmi sọ wọ́n di ahoro, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni OLúWA.’ “Nítorí náà, Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Israẹli kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ní ohun ti OLúWA Olódùmarè wí: Nínú èyí tí baba yín ti sọ̀rọ̀-òdì sí mi, nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀. Nítorí nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ náà, tí mo gbé ọwọ́ mi sókè láti fi í fún wọn, Nígbà náà ni wọ́n rí olúkúlùkù òkè gíga, àti gbogbo igi bíbò, wọ́n sì rú ẹbọ wọn níbẹ̀, wọ́n sì gbé ìmúnibínú ọrẹ wọ́n kalẹ̀ níbẹ̀; níbẹ̀ pẹ̀lú ni wọ́n ṣe òórùn dídùn wọn, wọ́n sì ta ohun ọrẹ mímu sílẹ̀ níbẹ̀, Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ̀yin lọ yìí?’ ” (Orúkọ rẹ̀ ni a sì ń pè ní Bama di òní yìí.) “Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli pé: ‘Èyí ní ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Ṣé o fẹ́ ba ara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, tiwọn ń ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra? Nígbà tí ẹ̀yin bá san ọrẹ yìí, ìrúbọ ọmọkùnrin ọmọ yín, tí ẹ mú ọmọ yin la iná kọjá, ẹ̀yin ń tẹ̀síwájú láti ba ara yín jẹ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà yín títí di òní yìí, ẹ̀yin yóò ha jẹ wádìí lọ́dọ̀ mi, ìwọ ilé Israẹli? Bí mo ti wà láààyè, ní OLúWA Olódùmarè wí, Èmi ki yóò jẹ́ kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi. “ ‘Ẹ̀yin wí pé, “Àwa fẹ́ dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, bí àwọn ènìyàn ayé, tó ń bọ igi àti òkúta.” Ṣùgbọ́n ohun ti ẹ ni lọ́kàn kò ní ṣẹ rárá. Bí mo ti wà láààyè, ní OLúWA Olódùmarè wí, Èmi yóò jẹ ọba lórí yín pẹ̀lú ọwọ́ agbára tí èmi yóò nà jáde pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná mi. Èmi yóò si mú yín jáde kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì ṣà yín jọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín sí pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà tí èmi yóò nà jáde àti pẹ̀lú ìtújáde ìbínú gbígbóná ni. Èmi yóò si mú yín wá sí aginjù àwọn orílẹ̀-èdè, níbẹ̀ ni ojúkójú ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ lé e yín lórí. Bí mo ṣe ṣe ìdájọ́ àwọn baba yín nínú aginjù nílẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní OLúWA Olódùmarè wí. Èmi yóò kíyèsi i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú Èmi yóò si ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ kúrò láàrín yín, àti àwọn o lù re òfin kọjá, èmi yóò mu wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ tiwọn gbé ṣe àtìpó, wọn ki yóò si wọ ilẹ̀ Israẹli: Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní OLúWA. “ ‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Israẹli, èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́. Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni OLúWA Olódùmarè wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Israẹli yóò sìn mí; èmi yóò sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ èmi yóò béèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín Èmi yóò tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín ká sí, èmi yóò sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrín yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní OLúWA, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Israẹli; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín. Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìṣesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti ṣe. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLúWA, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin Ilé Israẹli, ni OLúWA Olódùmarè wí.’ ” Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù. Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA. Èyí ní ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ, Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀. Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé Èmi OLúWA ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’ ” Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè! Wọn ń wí fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’ ”