Esek 14:3-8

Esek 14:3-8 Yoruba Bible (YCE)

ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi? “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada. “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ “Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn. N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

Esek 14:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti gbé òrìṣà kalẹ̀ sínú ọkàn wọn, wọ́n sì gbé àwọn ohun tó lè mú wọn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú wọn; Èmi yóò ha jẹ́ kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi rárá bí? Nítorí náà, sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tó gbé òrìṣà sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú rẹ̀, tí ó sì wá sọ́dọ̀ wòlíì; Èmi OLúWA fúnra mi ni yóò dá ẹni tí ó wa lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ. Èmi yóò ṣe èyí láti gba ọkàn àwọn ará Israẹli tó ti tẹ̀lé òrìṣà wọn lọ padà sí ọ̀dọ̀ mi.’ “Nítorí náà sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí: Ẹ ronúpìwàdà! Ẹ yípadà kúrò lọ́dọ̀ òrìṣà yín, kí ẹ̀yin sì kọ gbogbo ìwà ìríra yín sílẹ̀! “ ‘Bí ẹnikẹ́ni ní ilé Israẹli tàbí àlejò tó ń gbé ní ilẹ̀ Israẹli, bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tó gbé òrìṣà rẹ̀ sí ọkàn rẹ̀, tó tún gbé ohun tó mú ni ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ síwájú rẹ, lẹ́yìn èyí tó tún lọ sọ́dọ̀ wòlíì láti béèrè nǹkan lọ́wọ́ mi! Èmi OLúWA fúnra ara mi ní èmi yóò dá a lóhùn. Èmi yóò lòdì si irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lọ́nà òdì, Èmi yóò sì fi i ṣe ààmì àti òwe. Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn mi. Nígbà náà, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA.