Esek 14:13-14
Esek 14:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọ enia, nigbati ilẹ na ba ṣẹ̀ si mi nipa irekọja buburu, nigbana ni emi o nawọ mi le e, emi o si ṣẹ́ ọpa onjẹ inu rẹ̀, emi o si rán ìyan si i, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀: Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi.
Esek 14:13-14 Yoruba Bible (YCE)
“Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀, bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Esek 14:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ọmọ ènìyàn bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi nípa ìwà àìṣòdodo, èmi yóò nawọ́ mi jáde sí wọn, láti gé ìpèsè oúnjẹ wọn, èmi yóò rán ìyàn sí wọn, èmi yóò sì pa ènìyàn àti ẹranko inú rẹ̀, bí àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí—Noa, Daniẹli àti Jobu tilẹ̀ wà nínú rẹ, kìkì ẹ̀mí ara wọn nìkan ni wọ́n lé fi òdodo wọn gbàlà, OLúWA Olódùmarè wí.