Esek 12:1-28
Esek 12:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, iwọ ngbe ãrin ọlọ̀tẹ ile, ti nwọn ni oju lati ri, ti kò si ri; nwọn ni eti lati gbọ́, nwọn kò si gbọ́: nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn. Nitorina, iwọ ọmọ enia, mura nkan kikolọ, ki o si kó lọ li oju wọn li ọsan; ki o si kó lati ipò rẹ lọ si ibomiran li oju wọn; o le ṣe pe nwọn o ronu, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọ̀tẹ ile. Ki o si mu nkan rẹ jade li ọsan li oju wọn, bi nkan kikolọ; ki o si jade lọ li aṣalẹ li oju wọn, bi awọn ti nlọ si igbekùn. Da ogiri lu loju wọn, ki o si kó jade nibẹ. Li oju wọn ni ki o rù u le ejika rẹ, ki o si rù u lọ ni wiriwiri alẹ, ki o si bo oju rẹ, ki o má ba ri ilẹ; nitori mo ti gbe ọ kalẹ fun àmi si ile Israeli. Mo si ṣe bi a ti paṣẹ fun mi: mo mu nkan mi jade li ọsan, bi nkan fun igbekùn, mo si fi ọwọ́ mi dá ogiri lu li aṣalẹ; mo gbe e jade ni wiriwiri alẹ, mo si rù u le ejika mi loju wọn. Li owurọ ọ̀rọ Oluwa si ti tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, ile Israeli, ọlọ̀tẹ ile nì kò ti wi fun ọ pe, kini iwọ nṣe? Wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹrù yi hàn fun awọn ọmọ-alade ni Jerusalemu, ati gbogbo ile Israeli ti o wà lãrin wọn. Wipe, emi ni àmi nyin, gẹgẹ bi mo ti ṣe, bẹ̃ni a o si ṣe si wọn: nwọn o ko kuro, nwọn o si lọ si igbekùn. Ọmọ-alade ti o wà larin wọn yio si rẹrù lori ejika rẹ̀ ni wiriwiri alẹ, yio si jade lọ; nwọn o si dá ogiri lu lati kó jade nibẹ; yio si bo oju rẹ̀, ki o má ba fi oju rẹ̀ ri ilẹ. Awọ̀n mi ni emi o si tẹ́ le e lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi: emi o si mu u wá si Babiloni, si ilẹ awọn ara Kaldea; kì yio si ri i, bẹ̃ni yio kú nibẹ. Gbogbo awọn ti o yi i ka lati ràn a lọwọ, ati gbogbo ọwọ-ogun rẹ̀, ni emi o tuká si gbogbo afẹ̃fẹ, emi o si yọ idà le wọn. Nwọn o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa, nigbati mo ba tú wọn ka lãrin awọn orilẹ-ède; ti mo ba si fọ́n wọn ká ilẹ pupọ. Ṣugbọn emi o kù diẹ ninu wọn silẹ lọwọ idà, lọwọ iyàn, ati lọwọ ajakálẹ arùn; ki nwọn le sọ gbogbo ohun ẽri wọn lãrin awọn keferi, nibiti nwọn ba de; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, fi ìgbọnriri jẹ onjẹ rẹ, si fi ìwariri ati ikiyesara mu omi rẹ; Ki o si sọ fun awọn enia ilẹ na pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn ara Jerusalemu, niti ilẹ Israeli; nwọn o fi ikiyesara jẹ onjẹ wọn, nwọn o si fi iyanu mu omi wọn, ki ilẹ rẹ̀ ki o le di ahoro kuro ninu gbogbo ohun ti o wà ninu rẹ̀, nitori ìwa-ipá gbogbo awọn ti ngbe ibẹ̀. Awọn ilu ti a ngbe yio di ofo, ilẹ na yio si di ahoro; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, owe wo li ẹnyin ni, ni ilẹ Israeli pe, A fà ọjọ gùn, gbogbo iran di asan? Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o jẹ ki owe yi dẹkun, nwọn kì yio si pa a li owe ni Israeli mọ; ṣugbọn wi fun wọn pe, Ọjọ kù si dẹ̀dẹ; ati imuṣẹ gbogbo iran. Nitori kì yio si iran asan mọ, kì yio si si afọṣẹ ti npọnni ninu ile Israeli. Nitori emi li Oluwa: emi o sọ̀rọ, ọ̀rọ ti emi o sọ yio si ṣẹ, a kì yio fà a gùn mọ; nitori li ọjọ nyin, Ọlọtẹ ile, li emi o sọ ọ̀rọ na, emi o si ṣe e, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, kiyesi i, awọn ara ile Israeli wipe, Iran ti o ri, fun ọjọ pupọ ti mbọ̀ ni, o si sọ asọtẹlẹ akoko ti o jina rere. Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Kò si ọkan ninu ọ̀rọ mi ti a o fà gùn mọ, ṣugbọn ọ̀rọ ti mo ti sọ yio ṣẹ, ni Oluwa wi.

Esek 12:1-28 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ààrin àwọn olóríkunkun ni o wà: àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò fi gbọ́ràn, nítorí pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. “Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. Kó ẹrù rẹ jáde lójú wọn ní ọ̀sán gangan kí ìwọ pàápàá jáde lójú wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Dá odi ìlú lu níṣojú wọn, kí o sì gba ibẹ̀ jáde. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká níṣojú wọn, kí o sì jáde ní òru. Fi nǹkan bojú rẹ kí o má baà rí ilẹ̀, nítorí pé ìwọ ni mo ti fi ṣe àmì fún ilé Israẹli.” Mo ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi. Mo gbé ẹrù mi jáde lọ́sàn-án gangan bí ẹrù ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, mo fi ọwọ́ ara mi dá odi ìlú lu, mo sì gba ibẹ̀ jáde lóru. Mo gbé ẹrù mi lé èjìká níṣojú wọn. Ní òwúrọ̀, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi kò bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ni ò ń ṣe? Wí fún wọn pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá àwọn olórí Jerusalẹmu ati àwọn eniyan Israẹli tí ó kù ninu rẹ̀ wí.’ Sọ fún wọn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wọn. Bí o ti ṣe ni wọ́n óo ṣe wọ́n, wọn óo lọ sí ìgbèkùn. Ẹni tí ó jẹ́ olórí láàrin wọn yóo gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́, yóo sì jáde kúrò nílùú. Yóo dá odi ìlú lu, yóo gba ibẹ̀ jáde. Yóo fi nǹkan bojú kí ó má ba à rí ilẹ̀. N óo na àwọ̀n mi lé e lórí, yóo sì kó sinu tàkúté tí mo dẹ sílẹ̀. N óo mú un lọ sí Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea. Kò ní fi ojú rí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ibẹ̀ ni yóo kú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká ni n óo túká: gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni n óo sì jẹ́ kí ogun máa lé lọ. “Wọn óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá fọ́n wọn ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, tí mo tú wọn ká sórí ilẹ̀ ayé. N óo jẹ́ kí díẹ̀ ninu wọn bọ́ lọ́wọ́ ogun, ati ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, kí wọ́n lè ròyìn gbogbo ohun ìríra wọn láàrin àwọn tí wọn óo lọ máa gbé; wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ. Kí o wá sọ fún àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà pé, ‘OLUWA Ọlọrun sọ nípa àwọn ará Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹlu ìpayà ni wọn óo máa fi jẹun, tí wọn óo sì máa fi mu omi, nítorí pé ilẹ̀ wọn yóo di ahoro nítorí ìwà ipá tí àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń hù. Àwọn ìlú tí eniyan ń gbé yóo di òkítì àlàpà, gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ” OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, kí ló dé tí wọ́n máa ń pòwe ní ilẹ̀ Israẹli pé, ‘Ọjọ́ ń pẹ́ sí i, gbogbo ìran tí àwọn aríran rí sì já sí òfo.’ Nítorí náà, sọ fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní pa á ní ilẹ̀ Israẹli mọ́.’ Sọ fún wọn pé: Ọjọ́ ń súnmọ́lé tí gbogbo ìran àwọn aríran yóo ṣẹ. “Nítorí pé ìran irọ́ tabi àfọ̀ṣẹ ẹ̀tàn yóo dópin láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn èmi OLUWA yóo sọ ohun tí mo bá fẹ́ sọ, yóo sì ṣẹ. Kò ní falẹ̀ mọ́, ṣugbọn níṣojú ẹ̀yin ìdílé ọlọ̀tẹ̀, ni n óo sọ̀rọ̀, tí n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.” OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbọ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti ń wí pé, Ìran ọjọ́ iwájú ni ò ń rí, o sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ gbọọrọ. Nítorí náà, wí fún wọn pé: mo ní n kò ní fi ọ̀rọ̀ mi falẹ̀ mọ́, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ yóo ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.”
Esek 12:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, ìwọ ń gbé ní àárín ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn. Wọ́n lójú láti fi ríran, ṣùgbọ́n wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n létí láti fi gbọ́rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́rọ̀, torí pé ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn ni wọ́n. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, palẹ̀ ẹrù rẹ mọ́ láti lọ sí ìgbèkùn, ní ọ̀sán gangan ní ojú wọn, kúrò láti ibi tí ìwọ wà lọ sí ibòmíràn. Bóyá bí wọ́n bá rí ọ, wọn yóò sì ronú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n. Di ẹrù ìgbèkùn rẹ lójú wọn ní ọ̀sán án gangan, nígbà tí ó bá sì di alẹ́, ní ojú wọn, máa lọ sí ìgbèkùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lọ ìgbèkùn ṣe máa ń ṣe. Dá ògiri lu ní ojú wọn, kí ìwọ sì gba ibẹ̀ kó ẹrù rẹ jáde. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká ní ojú wọn, bo ojú rẹ, kí ìwọ má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ ní alẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe ààmì fún ilé Israẹli.” Mo ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún mi. Mo kó ẹrù mi jáde ní ọ̀sán án láti lọ fun ìgbèkùn. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, mo dá ògiri lu pẹ̀lú ọwọ́ mi. Mo sì gbe ẹrù mi lé èjìká nínú òkùnkùn ní ojú wọn. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, Ǹjẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé Israẹli tilẹ̀ bi ọ́ pé, ‘Kí ni ohun tí o ń ṣe túmọ̀ sí?’ “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ-aládé Jerusalẹmu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó wà ní àárín rẹ. Sọ fún wọn pé, Èmi jẹ́ ààmì fún yín’. “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn. “Ọmọ-aládé tí ó wà ní àárín wọn yóò di ẹrù rẹ̀ lé èjìká ní alẹ́ yóò sì jáde lọ, òun náà yóò da ògiri lu kí ó le gba ibẹ̀ jáde. Yóò sì bo ojú rẹ̀ kí ó má ba à rí ilẹ̀. Èmi yóò ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, Èmi yóò sì mú lọ sí Babeli, ní ilẹ̀ Kaldea, ṣùgbọ́n kò ní fojúrí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí. Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ni Èmi yóò túká sí afẹ́fẹ́, èmi yóò sì tún fi idà lé wọn kiri. “Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni OLúWA nígbà tí mo bá tú wọn ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri. Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, ní ọwọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLúWA.” Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà. Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀. Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni OLúWA.’ ” Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá pé: “Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’? Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ. Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ tí ó ń pọ́n ni mọ́ ní àárín ilé Israẹli. Ṣùgbọ́n Èmi OLúWA yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ” Ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá pé: “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ìwọ rí, ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’ “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún síwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’ ”