Eks 9:1-35
Eks 9:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn le sìn mi. Nitoripe, bi iwọ ba kọ̀ lati jẹ ki nwọn lọ, ti iwọ si da wọn duro sibẹ̀, Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀. OLUWA yio si pàla si agbedemeji ẹran-ọ̀sin Israeli ati ẹran-ọ̀sin Egipti: kò si ohun kan ti yio kú ninu gbogbo eyiti iṣe ti awọn ọmọ Israeli. OLUWA si dá akokò kan wipe, Li ọla li OLUWA yio ṣe nkan yi ni ilẹ yi. OLUWA si ṣe nkan na ni ijọ́ keji, gbogbo ẹran-ọ̀sin Egipti si kú: ṣugbọn ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli ọkanṣoṣọ kò si kú. Farao si ranṣẹ, si kiyesi i, ọkanṣoṣo kò kú ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli. Àiya Farao si le, kò si jẹ ki awọn enia na ki o lọ. OLUWA si wi fun Mose ati fun Aaroni pe, Bù ikunwọ ẽru ninu ileru, ki Mose ki o kù u si oju-ọrun li oju Farao. Yio si di ekuru lẹbulẹbu ni gbogbo ilẹ Egipti, yio si di õwo ti yio ma tú pẹlu ileròro lara enia, ati lara ẹran, ká gbogbo ilẹ Egipti. Nwọn si bù ẽru ninu ileru, nwọn duro niwaju Farao; Mose si kù u si oke ọrun; o si di õwo ti o ntú jade pẹlu ileròro lara enia ati lara ẹran. Awọn alalupayida kò si le duro niwaju Mose nitori õwo wọnni; nitoriti õwo na wà lara awọn alalupayida, ati lara gbogbo awọn ara Egipti. OLUWA si mu àiya Farao le, kò si gbọ́ ti wọn; bi OLUWA ti sọ fun Mose. OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ ki nwọn le sìn mi. Nitori ìgba yi li emi o rán gbogbo iyọnu mi si àiya rẹ, ati sara awọn iranṣẹ rẹ, ati sara awọn enia rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe kò si ẹlomiran bi emi ni gbogbo aiye. Nitori nisisiyi, emi iba nà ọwọ́ mi, ki emi ki o le fi ajakalẹ-àrun lù ọ, ati awọn enia rẹ; a ba si ti ke ọ kuro lori ilẹ. Ṣugbọn nitori eyi pãpa li emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi hàn lara rẹ; ati ki a le ròhin orukọ mi ká gbogbo aiye. Titi di isisiyi iwọ ngbé ara rẹ ga si awọn enia mi pe, iwọ ki yio jẹ ki nwọn ki o lọ? Kiyesi i, li ọla li akokò yi, li emi o mu ọ̀pọ yinyin rọ̀ si ilẹ, irú eyiti kò ti si ni Egipti lati ipilẹṣẹ rẹ̀ titi o fi di isisiyi. Njẹ nisisiyi ranṣẹ, ki o si kó ẹran rẹ bọ̀, ati ohun gbogbo ti o ni ninu oko; nitori olukuluku enia ati ẹran ti a ba ri li oko, ti a kò si múbọ̀ wá ile, yinyin yio bọ lù wọn, nwọn o si kú. Ẹniti o bẹ̀ru ọ̀rọ OLUWA ninu awọn iranṣẹ Farao, mu ki awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ sá padà wá ile: Ẹniti kò si kà ọ̀rọ OLUWA si, jọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ si oko. OLUWA si sọ fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si oke ọrun, ki yinyin ki o le bọ́ si gbogbo ilẹ Egipti, sara enia, ati sara ẹranko, ati sara eweko igbẹ́ gbogbo, já gbogbo ilẹ Egipti. Mose si nà ọpá rẹ̀ si ọrun: OLUWA si rán ãra ati yinyin, iná na si njó lori ilẹ; OLUWA si rọ̀ yinyin sori ilẹ Egipti. Yinyin si bọ́, iná si dàpọ mọ́ yinyin na, o papọ̀ju, irú rẹ̀ kò si ri ni gbogbo ilẹ Egipti lati ìgba ti o ti di orilẹ-ède. Yinyin na si lù ohun gbogbo ti o wà ninu oko bolẹ, ati enia ati ẹranko, já gbogbo ilẹ Egipti; yinyin na si lù gbogbo eweko bolẹ, o si fà gbogbo igi igbẹ́ ya. Ni kìki ilẹ Goṣeni, nibiti awọn ọmọ Israeli gbé wà, ni yinyin kò si. Farao si ranṣẹ, o si pè Mose ati Aaroni, o si wi fun wọn pe, Emi ṣẹ̀ nigbayi: OLUWA li olododo, ẹni buburu si li emi ati awọn enia mi. Ẹ bẹ̀ OLUWA (o sa to) ki ãra nla ati yinyin wọnyi ki o máṣe si mọ́; emi o si jẹ ki ẹ ma lọ; ẹ ki yio si duro mọ́. Mose si wi fun u pe, Bi mo ba ti jade ni ilu, emi o tẹ́ ọwọ́ mi si OLUWA; ãra yio si dá, bẹ̃ni yinyin ki yio si mọ́; ki iwọ ki o le mọ̀ pe ti OLUWA li aiye. Ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni ati ti awọn iranṣẹ rẹ, emi mọ̀ pe sibẹ, ẹnyin kò ti ibẹ̀ru OLUWA Ọlọrun. A si lù ọgbọ́ ati ọkà barle bolẹ; nitori ọkà barle wà ni ipẹ́, ọgbọ́ si rudi. Ṣugbọn alikama ati ọkà (rie) li a kò lù bolẹ: nitoriti nwọn kò ti idàgba. Mose si jade kuro lọdọ Farao sẹhin ilu, o si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ si OLUWA; ãra ati yinyin si dá, bẹ̃li òjo kò si rọ̀ si ilẹ̀ mọ́. Nigbati Farao ri pe, òjo ati yinyin ati ãra dá, o ṣẹ̀ si i, o si sé àiya rẹ̀ le, on ati awọn iranṣẹ rẹ̀. Àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ; bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.
Eks 9:1-35 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun. Ati pé, bí ó bá kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀. Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA bá dá àkókò kan, ó ní, “Ní ọ̀la ni èmi OLUWA, yóo ṣe ohun tí mo wí yìí ní ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí ó di ọjọ́ keji OLUWA ṣe bí ó ti wí; gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti kú, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo kò kú ninu ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Farao bá ranṣẹ lọ wo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì rí i pé ẹyọ kan kò kú ninu wọn. Sibẹsibẹ ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé kí wọn bu ẹ̀kúnwọ́ eérú bíi mélòó kan ninu ẹbu, kí Mose dà á sí ojú ọ̀run lójú Farao, yóo sì di eruku lẹ́búlẹ́bú lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti, yóo di oówo tí yóo máa di egbò lára eniyan ati ẹranko, ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko. Àwọn pidánpidán kò lè dúró níwájú Mose, nítorí pe oówo bo àwọn náà ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn OLUWA mú kí ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose. OLUWA tún sọ fún Mose pé kí ó dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ó lọ siwaju Farao, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sin òun. Nítorí pé lọ́tẹ̀ yìí, òun óo da gbogbo àjàkálẹ̀ àrùn òun bo Farao gan-an, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati àwọn eniyan rẹ̀, kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó dàbí òun OLUWA ní gbogbo ayé. Kí ó ranti pé, bí òun OLUWA ti nawọ́ ìyà sí òun ati àwọn eniyan rẹ̀, tí òun sì ti da àjàkálẹ̀ àrùn bò wọ́n; òun ìbá ti pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé. Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ. OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí. Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.” Nítorí náà gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLUWA ninu àwọn iranṣẹ Farao pe àwọn ẹrú wọn wálé, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wálé pẹlu. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí fi àwọn ẹrú ati àwọn ohun ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ninu pápá. OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sójú ọ̀run, kí yìnyín lè bọ́ kí ó sì bo ilẹ̀ Ijipti, ati eniyan, ati ẹranko, ati gbogbo ewéko inú ìgbẹ́.” Mose bá na ọ̀pá rẹ̀ sójú ọ̀run, Ọlọrun sì da ààrá ati yìnyín ati iná bo ilẹ̀, Ọlọrun sì rọ̀jò yìnyín sórí ilẹ̀ Ijipti. Yìnyín ń bọ́, mànàmáná sì ń kọ yànràn ninu yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́; kò tíì sí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè. Gbogbo ohun tí ó wà ninu oko ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ni yìnyín náà dà lulẹ̀, ati eniyan ati ẹranko; o sì wó gbogbo àwọn ohun ọ̀gbìn oko ati gbogbo igi lulẹ̀. Àfi ilẹ̀ Goṣeni, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé nìkan ni yìnyín yìí kò dé. Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni, ó sọ fún wọn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀ nisinsinyii; OLUWA jàre, èmi ati àwọn eniyan mi ni a jẹ̀bi. Ẹ bẹ OLUWA fún mi nítorí pé yìnyín ati ààrá yìí tó gẹ́ẹ́, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n kò ní da yín dúró mọ́.” Mose bá dá Farao lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ninu ìlú n óo gbadura sí OLUWA, ààrá kò ní sán mọ́, bẹ́ẹ̀ ni yìnyín kò ní bọ́ mọ́, kí o lè mọ̀ pé, ti OLUWA ni ilẹ̀. Ṣugbọn mo mọ̀ pé ìwọ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ kò bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun.” Gbogbo ọ̀gbọ̀ ati ọkà Baali tí ó wà lóko ni ó ti bàjẹ́ patapata, nítorí pé ọkà baali ati ọ̀gbọ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí so ni. Ṣugbọn ọkà alikama ati ọkà ria kò bàjẹ́, nítorí pé wọn kò tètè hù. Mose bá kúrò lọ́dọ̀ Farao, ó jáde kúrò ní ìlú; ó gbadura sí OLUWA, ààrá tí ń sán ati yìnyín tí ń bọ́ sì dáwọ́ dúró, òjò náà sì dá lórí ilẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí Farao rí i pé òjò ti dá, ati pé yìnyín ati ààrá ti dáwọ́ dúró, ó tún dẹ́ṣẹ̀, ọkàn rẹ̀ tún le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Mose.
Eks 9:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Lọ sọ fún Farao, ‘Èyí ni OLúWA Ọlọ́run àwọn Heberu sọ: “Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn Mí” Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, tí ó sì dá wọn dúró. Ọwọ́ OLúWA yóò mú ààrùn búburú wá sí ara ẹran ọ̀sìn nínú oko, sí ara ẹṣin, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìbákasẹ, màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́ yín. Ṣùgbọ́n OLúWA yóò pààlà sí àárín ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ ti Israẹli àti ti àwọn ara Ejibiti tí yóò fi jẹ́ pé kò sí ẹran ọ̀sìn ti ó jẹ́ ti ará Israẹli tí yóò kùú.’ ” OLúWA sì dá àkókò kan wí pé, “Ní ọ̀la ni OLúWA yóò ṣe èyí ni ilẹ̀ yìí.” OLúWA sí ṣe é ni ọjọ́ kejì. Gbogbo ẹran ọ̀sìn ará Ejibiti kú, ṣùgbọ́n ẹyọ kan kò kú lára ẹran ọ̀sìn àwọn Israẹli. Farao rán àwọn ènìyàn rẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí, wọ́n sì rí pé ẹyọ kan kò kú lára àwọn ẹran ọ̀sìn ará Israẹli. Síbẹ̀ náà, Farao kò yí ọkàn rẹ̀ padà àti pé kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni, “Ẹ bu ẹ̀kúnwọ́ eérú gbígbóná láti inú ààrò, kí Mose kù ú sí inú afẹ́fẹ́ ni iwájú Farao. Yóò sì di eruku lẹ́búlẹ́bú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, yóò sì di oówo ti ń tú pẹ̀lú ìléròrò sí ara àwọn ènìyàn àti ẹran jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran. Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ fún Mose. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run àwọn Heberu wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí, Nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé. Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé. Síbẹ̀ ìwọ tún gbógun ti àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì jẹ́ kí wọn lọ. Nítorí náà, ni ìwòyí ọ̀la, Èmi yóò rán òjò o yìnyín tí irú rẹ̀ kò tí i rọ̀ rí ni Ejibiti láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ títí di àkókò yìí. Pàṣẹ nísinsin yìí láti kó ẹran ọ̀sìn yín àti ohun gbogbo ti ẹ ni ní pápá wá sí abẹ́ ààbò, nítorí òjò yìnyín yóò rọ̀ sí orí àwọn ènìyàn àti ẹran ti a kò kó wá sí abẹ́ ààbò tí wọ́n sì wà ni orí pápá, wọn yóò sì kú.’ ” Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLúWA lára àwọn ìjòyè Farao yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò. Ṣùgbọ́n àwọn ti kò kà ọ̀rọ̀ OLúWA sí fi àwọn ẹrú wọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ni pápá. OLúWA sọ fún Mose pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ọ̀run kí yìnyín bá à lè rọ̀ sí orí gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, sí orí ènìyàn àti ẹranko, àti sí orí gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko.” Nígbà tí Mose gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí ojú ọ̀run, OLúWA rán àrá àti yìnyín, mọ̀nàmọ́ná sì bùsi orí ilẹ̀. OLúWA rọ òjò yìnyín sí orí ilẹ̀ Ejibiti; Yìnyín rọ̀, mọ̀nàmọ́ná sì bẹ̀rẹ̀ sí bùsi orí ilẹ̀ èyí ni ó tí ì burú jù ti ó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ti Ejibiti ti di orílẹ̀-èdè. Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti ni yìnyín ti pa gbogbo ohun tí ó wà ni orí pápá; ènìyàn àti ẹranko, ó wò gbogbo ohun ọ̀gbìn lulẹ̀ ó sì fa gbogbo igi ya pẹ̀lú. Ilẹ̀ Goṣeni ni ibi ti àwọn Israẹli wà nìkan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé. Nígbà náà ni Farao pe Mose àti Aaroni sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; OLúWA jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìṣòdodo. Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí OLúWA kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.” Mose dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúrò ní àárín ìlú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí OLúWA, sísán àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé OLúWA ni ó ni ilẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run.” (A sì lu ọ̀gbọ̀ àti ọkà barle bolẹ̀; nítorí barle wà ní ìpẹ́, ọ̀gbọ̀ sì rudi. Alikama àti ọkà ni a kò lù bolẹ̀, nítorí tí wọ́n kò tí ì dàgbà.) Nígbà náà ni Mose jáde kúrò ni iwájú Farao, ó kúrò ni àárín ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí OLúWA, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́. Nígbà tí Farao rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣì sé àyà wọn le. Àyà Farao sì le, bẹ́ẹ̀ ni kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, bí OLúWA ti sọ láti ẹnu Mose.