Eks 7:14-25
Eks 7:14-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ. Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ. Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́. Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ. Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na. OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta. Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ. Ẹja ti o wà li odò si kú; odò na si nrùn, awọn ara Egipti kò si le mu ninu omi odò na; ẹ̀jẹ si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, Awọn alalupayida Egipti si fi idán wọn ṣe bẹ̃: àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi. Farao si pada o lọ si ile rẹ̀, kò si fi ọkàn rẹ̀ si eyi pẹlu. Gbogbo awọn ara Egipti si wàlẹ yi odò na ká fun omi mimu; nitoriti nwọn kò le mu ninu omi na. Ọjọ́ meje si pé, lẹhin igbati OLUWA lù odò na.
Eks 7:14-25 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA wí fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ. Tọ Farao lọ ní òwúrọ̀, bí ó bá ti ń jáde lọ sí etídò, kí o dúró dè é ní etí bèbè odò, kí o sì mú ọ̀pá tí ó di ejò lọ́wọ́. Sọ fún un pé, ‘OLUWA, Ọlọrun àwọn Heberu rán mi sí ọ, pé kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, kí wọ́n lè sin òun ní aṣálẹ̀, sibẹ o kò gbọ́. OLUWA wí pé ohun tí o óo fi mọ̀ pé òun ni OLUWA nìyí: n óo fi ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ mi yìí lu odò Naili, omi odò náà yóo sì di ẹ̀jẹ̀. Gbogbo ẹja inú odò náà yóo kú, odò náà yóo sì máa rùn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò ní lè mu omi inú rẹ̀ mọ́.’ ” OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó mú ọ̀pá rẹ̀, kí ó sì nà án sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ati sórí odò wọn, ati sórí adágún tí wọ́n gbẹ́, ati gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí wọ́n lè di ẹ̀jẹ̀, ẹ̀jẹ̀ yóo sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti; ati omi tí ó wà ninu agbada tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati tinú agbada tí wọ́n fi òkúta gbẹ́.” Mose ati Aaroni ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA lójú Farao ati lójú gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Aaroni gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ó sì fi lu omi tí ó wà ninu odò Naili, gbogbo omi tí ó wà ninu odò náà sì di ẹ̀jẹ̀. Gbogbo ẹja tí ó wà ninu odò náà kú, odò sì bẹ̀rẹ̀ sí rùn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Ijipti kò fi lè mu omi rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà níbi gbogbo jákèjádò ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn àwọn pidánpidán ilẹ̀ Ijipti lo ọgbọ́n idán wọn, àwọn náà ṣe bí Mose ati Aaroni ti ṣe, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn Farao túbọ̀ yigbì sí i, kò sì gbọ́ ohun tí Mose ati Aaroni wí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, Farao yipada, ó lọ sí ilé, kò ka ọ̀rọ̀ náà sí rara. Gbogbo àwọn ará Ijipti bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́lẹ̀ káàkiri yíká odò Naili, pé bóyá wọn á jẹ́ rí omi mímu nítorí pé wọn kò lè mu omi odò Naili mọ́. Ọjọ́ meje kọjá, lẹ́yìn tí OLUWA ti fi ọ̀pá lu odò Naili.
Eks 7:14-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ. Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ. Sọ fún un pé, ‘OLúWA Ọlọ́run àwọn Heberu rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni aginjù. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba. Èyí ni OLúWA wí: Nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀. Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Naili yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Ejibiti kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ” OLúWA sọ fún Mose, “Sọ fún Aaroni, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Ejibiti. Lórí àwọn odò kéékèèkéé àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi, wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Ejibiti, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.” Mose àti Aaroni sí ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Naili, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀. Ẹja inú odò Naili sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Ejibiti kò le è mu omi inú rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Ejibiti. Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Ejibiti sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Farao sì yigbì síbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Naili láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà. Ọjọ́ méje sì kọjá ti OLúWA ti lu odò Naili.