Eks 6:5-8
Eks 6:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi si ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sìn; emi si ti ranti majẹmu mi. Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde: Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti. Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA.
Eks 6:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá. N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín. N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ”
Eks 6:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú Mi. “Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli: ‘Èmi ni OLúWA, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá. Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Abrahamu. Isaaki àti Jakọbu. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, Èmi ni OLúWA.’ ”