Eks 5:1-9

Eks 5:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù. Farao si wipe, Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ lati jẹ ki Israeli ki o lọ? Emi kò mọ̀ OLUWA na, bẹ̃li emi ki yio jẹ ki Israeli ki o lọ. Nwọn si wipe, Ọlọrun awọn Heberu li o pade wa: awa bẹ̀ ọ, jẹ ki a lọ ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa; ki o má ba fi ajakalẹ-àrun tabi idà kọlù wa. Ọba Egipti si wi fun wọn pe, Mose ati Aaroni, nitori kili ẹnyin ṣe dá awọn enia duro ninu iṣẹ wọn? ẹ lọ si iṣẹ nyin. Farao si wipe, Kiyesi i awọn enia ilẹ yi pọ̀ju nisisiyi, ẹnyin si mu wọn simi kuro ninu iṣẹ wọn. Farao si paṣẹ li ọjọ́ na fun awọn akoniṣiṣẹ awọn enia, ati fun awọn olori wọn wipe, Ẹnyin kò gbọdọ fun awọn enia na ni koriko mọ́ lati ma ṣe briki, bi ìgba atẹhinwá: jẹ ki nwọn ki o ma lọ ṣà koriko fun ara wọn. Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa. Ẹ jẹ ki iṣẹ ki o wuwo fun awọn ọkunrin na, ki nwọn ki o le ma ṣe lãlã ninu rẹ̀; ẹ má si ṣe jẹ ki nwọn ki o fiyesi ọ̀rọ eke.

Eks 5:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ” Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọlọrun àwọn Heberu ni ó farahàn wá; jọ̀wọ́, fún wa ní ààyè láti lọ sí aṣálẹ̀ ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó má baà fi àjàkálẹ̀ àrùn tabi ogun bá wa jà.” Ṣugbọn ọba Ijipti dá wọn lóhùn pé, “Ìwọ Mose ati ìwọ Aaroni, kí ló dé tí ẹ fi kó àwọn eniyan wọnyi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ kó wọn pada kíákíá.” Farao fi kún un pé, “Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àwọn eniyan yìí pọ̀ pupọ ju àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí lọ, ẹ sì tún kó wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn?” Ní ọjọ́ náà gan-an ni Farao pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọ̀gá tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ fún àwọn eniyan wọnyi ní koríko láti fi ṣe bíríkì bí ẹ ti ṣe ń fún wọn tẹ́lẹ̀ mọ; ẹ jẹ́ kí wọn máa lọ kó koríko fúnra wọn. Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’ Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.”

Eks 5:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ” Farao dáhùn wí pé, “Ta ni OLúWA, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ OLúWA, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.” Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Heberu tí pàdé wa. Ní ìsinsin yìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí OLúWA Ọlọ́run wa, kí Ó má ba á fi àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí idà bá wa jà.” Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti sọ wí pé, “Mose àti Aaroni, èéṣe ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.” Nígbà náà ni Farao sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsin yìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.” Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn. “Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì sísun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’ Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”