Eks 5:1-2
Eks 5:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù. Farao si wipe, Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ lati jẹ ki Israeli ki o lọ? Emi kò mọ̀ OLUWA na, bẹ̃li emi ki yio jẹ ki Israeli ki o lọ.
Eks 5:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ” Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.”
Eks 5:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ” Farao dáhùn wí pé, “Ta ni OLúWA, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ OLúWA, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”