Eks 39:1-7
Eks 39:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NWỌN si fi ninu aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, dá aṣọ ìsin, lati ma fi sìn ni ibi mimọ́, nwọn si dá aṣọ mimọ́ ti iṣe fun Aaroni; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. O si ṣe ẹ̀wu-efodi na ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ. Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì. Nwọn ṣe aṣọ ejika si i, lati so o lù: li eti mejeji li a so o lù. Ati onirũru-ọnà ọjá ti o wà lara rẹ̀, lati fi dì i o jẹ́ ọkanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, aṣọ-alaró, elesè-àluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si. O si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi na, li okuta, iranti fun awọn ọmọ Israeli: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Eks 39:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, rán ẹ̀wù aláràbarà tí àwọn alufaa yóo máa wọ̀ ninu ibi mímọ́ náà fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ rán efodu. Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Wọ́n ṣe aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ meji fún èjìká efodu náà, wọ́n rán wọn mọ́ ẹ̀gbẹ́ kinni keji rẹ̀ láti máa fi so wọ́n mọ́ ara wọn. Wọ́n fi irú aṣọ kan náà ṣe àmùrè dáradára kan. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é mọ́ efodu yìí láti máa fi so ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì. Ó tò wọ́n sí ara èjìká efodu náà gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Eks 39:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó ṣe ẹ̀wù efodu wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára, iṣẹ́ ọlọ́nà. Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù efodu náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so ó pọ̀. Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose.