Eks 37:1-9
Eks 37:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
BESALELI si fi igi ṣittimu ṣe apoti na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: O si fi kìki wurà bò o ninu ati lode, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. O si dà oruka wurà mẹrin fun u, lati fi si igun mẹrẹrin rẹ̀; oruka meji si ìha kini rẹ̀, ati meji si ìha keji rẹ̀. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá, o si fi wurà bò wọn. O si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, lati ma rù apoti na. O si fi kìki wurà ṣe itẹ́-ãnu na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀. O si ṣe kerubu wurà meji; iṣẹ lilù li o ṣe wọn, ni ìku mejeji itẹ́-ãnu na; Kerubu kan ni ìku kini, ati kerubu keji ni ìku keji: lati ara itẹ́-ãnu li o ti ṣe awọn kerubu na ni ìku mejeji rẹ̀. Awọn kerubu na si nà iyẹ́-apa wọn soke, nwọn si fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, nwọn si dojukọ ara wọn; itẹ́-ãnu na ni awọn kerubu kọjusi.
Eks 37:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà, Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji. Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú.
Eks 37:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.