Eks 37:1-24
Eks 37:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
BESALELI si fi igi ṣittimu ṣe apoti na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: O si fi kìki wurà bò o ninu ati lode, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. O si dà oruka wurà mẹrin fun u, lati fi si igun mẹrẹrin rẹ̀; oruka meji si ìha kini rẹ̀, ati meji si ìha keji rẹ̀. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá, o si fi wurà bò wọn. O si fi ọpá wọnni bọ̀ inu oruka wọnni ni ìha apoti na, lati ma rù apoti na. O si fi kìki wurà ṣe itẹ́-ãnu na: igbọnwọ meji on àbọ ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibú rẹ̀. O si ṣe kerubu wurà meji; iṣẹ lilù li o ṣe wọn, ni ìku mejeji itẹ́-ãnu na; Kerubu kan ni ìku kini, ati kerubu keji ni ìku keji: lati ara itẹ́-ãnu li o ti ṣe awọn kerubu na ni ìku mejeji rẹ̀. Awọn kerubu na si nà iyẹ́-apa wọn soke, nwọn si fi iyẹ́-apa wọn bò itẹ́-ãnu na, nwọn si dojukọ ara wọn; itẹ́-ãnu na ni awọn kerubu kọjusi. O si fi igi ṣittimu ṣe tabili kan: igbọnwọ meji ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀, igbọnwọ kan on àbọ si ni giga rẹ̀: O si fi kìki wurà bò o, o si ṣe igbáti wurà si i yiká. O si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, o si ṣe igbáti wurà kan fun eti rẹ̀ yiká. O si dà oruka wurà mẹrin fun u, o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà ni ibi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rẹ̀. Labẹ igbáti na ni oruka wọnni wà, àye fun ọpá lati fi rù tabili na. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi wurà bò wọn, lati ma rù tabili na. O si ṣe ohunèlo wọnni ti o wà lori tabili na, awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati awokòto rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, lati ma fi dà ohun mimu, kìki wurà ni. O si fi kìki wurà, ṣe ọpá-fitila: iṣẹ lilù li o ṣe ọpá-fitila na; ọpá rẹ̀, ati ẹka rẹ̀, ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn: Ẹka mẹfa li o jade ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan rẹ̀, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na, ni ìha keji rẹ̀. Ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka kan, irudi kan ati itanna; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka keji, irudi kan ati itanna: bẹ̃ni li ẹka mẹfẹfa ti o jade lara ọpá-fitila na. Ati ninu ọpá-fitila na li a ṣe ago mẹrin bi itanna almondi, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀: Ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, ati irudi kan nisalẹ ẹka meji lara rẹ̀, gẹgẹ bi ẹka mẹfẹfa ti o jade lara rẹ̀. Irudi wọn ati ẹka wọn jẹ bakanna: gbogbo rẹ̀ jẹ́ iṣẹ lilù kìki wurà kan. O si ṣe fitila rẹ̀, meje, ati alumagaji rẹ̀, ati awo rẹ̀, kìki wurà ni. Talenti kan kìki wurà li o fi ṣe e, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀.
Eks 37:1-24 Yoruba Bible (YCE)
Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà, Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji. Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú. Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. Ìgbátí tí ó ṣe náà fẹ̀ ní àtẹ́lẹwọ́ kan ati ààbọ̀. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin tabili náà lábẹ́ ìgbátí rẹ̀, àwọn òrùka yìí ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá tí wọ́n fi máa ń gbé tabili náà, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá ìgbámú rẹ̀, àṣepọ̀ ni ó ṣe é, pẹlu àwọn fìtílà rẹ̀, ati àwọn kinní kan bí òdòdó tí ó fi dárà sí i lára. Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà. Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀. Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta. Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n. Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà. Odidi talẹnti wúrà marundinlaadọrin ni ó lò lórí ọ̀pá fìtílà yìí ati àwọn ohun èlò tí wọ́n jẹ mọ́ ti ọ̀pá fìtílà.
Eks 37:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́. Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga. Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà. Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde. Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà ní ojúlówó wúrà, ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, ìrudí rẹ àti agogo rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà. Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. Àwo mẹ́ta ni a ṣe bí ìtànná almondi pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà. Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà. Ó ṣe fìtílà rẹ̀, méje, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo rẹ̀, kìkì wúrà ni. Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara tálẹ́ǹtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà.