Eks 32:15-26

Eks 32:15-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

Mose si yipada, o si sọkalẹ lati ori òke na wá, walã ẹrí meji nì si wà li ọwọ́ rẹ̀; walã ti a kọwe si ni ìha mejeji; lara ekini ati ekeji li a kọwe si. Iṣẹ́ Ọlọrun si ni walã wọnni, ikọwe na ni ikọwe Ọlọrun, a fin i sara walã na. Nigbati Joṣua si gbọ́ ariwo awọn enia na, bi nwọn ti nhó, o wi fun Mose pe, Ariwo ogun mbẹ ni ibudó. Mose si wi pe, Ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nhó nitori iṣẹgun, bẹ̃ni ki iṣe ohùn ariwo awọn ti nkigbe pe a ṣẹgun wọn: ohùn awọn ti nkọrin ni mo gbọ́ yi. O si ṣe, bi o ti sunmọ ibudó, o si ri ẹgbọrọmalu na, ati agbo ijó: ibinu Mose si ru gidigidi, o si sọ walã wọnni silẹ kuro li ọwọ́ rẹ̀, o si fọ́ wọn nisalẹ òke na. O si mú ẹgbọrọ-malu na ti nwọn ṣe, o si sun u ni iná, o si lọ̀ ọ di ẹ̀tu, o si kù u soju omi, o si mu awọn ọmọ Israeli mu u. Mose si wi fun Aaroni pe, Kili awọn enia wọnyi fi ṣe ọ, ti iwọ fi mú ẹ̀ṣẹ̀ nla wá sori wọn? Aaroni si wipe, Máṣe jẹ ki ibinu oluwa mi ki o gbona: iwọ mọ̀ awọn enia yi pe, nwọn buru. Awọn li o sa wi fun mi pe, Ṣe oriṣa fun wa, ti yio ma ṣaju wa: bi o ṣe ti Mose yi ni, ọkunrin nì ti o mú wa gòke lati ilẹ Egipti wá, awa kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. Emi si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba ni wurà, ki nwọn ki o kán a kuro; bẹ̃ni nwọn fi fun mi: nigbana li emi fi i sinu iná, ẹgbọrọmalu yi si ti jade wá. Nigbati Mose ri i pe awọn enia na kò ṣe ikoso; nitoriti Aaroni sọ wọn di alailakoso lãrin awọn ti o dide si wọn. Nigbana ni Mose duro li ẹnubode ibudó, o si wipe, Ẹnikẹni ti o wà ni ìha ti OLUWA, ki o tọ̀ mi wá. Gbogbo awọn ọmọ Lefi si kó ara wọn jọ sọdọ rẹ̀.

Eks 32:15-26 Yoruba Bible (YCE)

Mose bá yipada, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, tòun ti wàláà òkúta ẹ̀rí mejeeji lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn wàláà òkúta tí Ọlọrun ti kọ nǹkan sí lójú mejeeji. Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn wàláà òkúta náà, Ọlọrun tìkararẹ̀ ni ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára wọn. Bí Joṣua ti gbọ́ ariwo àwọn eniyan náà tí wọn ń ké, ó wí fún Mose pé, “Ariwo ogun wà ninu àgọ́.” Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “Èyí kì í ṣe ìhó ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe igbe ẹni tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, ìró orin ni èyí tí mò ń gbọ́ yìí.” Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà. Ó mú ère ọmọ mààlúù náà, tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sun ún níná, ó lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, ó kù ú sójú omi, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Israẹli mu. Mose bi Aaroni pé, “Kí ni àwọn eniyan wọnyi fi ṣe ọ́, tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá yìí wá sórí wọn?” Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n, àwọn ni wọ́n wá bá mi tí wọ́n ní, ‘Ṣe oriṣa fún wa tí yóo máa ṣáájú wa lọ, nítorí pé a kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Mose, tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.’ Ni mo bá wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Wọ́n kó wọn fún mi, ni mo bá dà wọ́n sinu iná, òun ni mo sì fi yá ère mààlúù yìí.” Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn, Mose bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ní, “Ẹ̀yin wo ni ẹ̀ ń ṣe ti OLUWA, ẹ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ọmọ Lefi bá kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

Eks 32:15-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin. Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà. Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.” Mose dáhùn pé: “Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun, kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun; ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.” Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà. Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún. Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?” Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’ Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!” Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún OLúWA, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.