Eks 3:4 - Compare All Versions

Eks 3:4 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nigbati OLUWA ri pe, o yipada si apakan lati wò o, Ọlọrun kọ si i lati inu ãrin igbẹ́ na wá, o si wipe, Mose, Mose. On si dahun pe, Emi niyi.

Eks 3:4 YCE (Yoruba Bible)

Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!” Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

Eks 3:4 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà tí OLúWA rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!” Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”