Eks 3:1-4
Eks 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun. Angeli OLUWA si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati inu ãrin igbẹ̀: on si wò, si kiyesi i, iná njó igbẹ́, igbẹ́ na kò si run. Mose si wipe, Njẹ emi o yipada si apakan, emi o si wò iran nla yi, ẽṣe ti igbẹ́ yi kò run. Nigbati OLUWA ri pe, o yipada si apakan lati wò o, Ọlọrun kọ si i lati inu ãrin igbẹ́ na wá, o si wipe, Mose, Mose. On si dahun pe, Emi niyi.
Eks 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun. Angẹli OLUWA farahàn án ninu ahọ́n iná láàrin ìgbẹ́; bí ó ti wò ó, ó rí i pé iná ń jó nítòótọ́, ṣugbọn igbó náà kò jóná. Mose bá wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo súnmọ́ kinní yìí, mo fẹ́ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná fi ń jó tí igbó kò sì fi jóná.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!” Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
Eks 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀ ni angẹli OLúWA ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.” Nígbà tí OLúWA rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!” Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”