Eks 3:1-2
Eks 3:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun. Angeli OLUWA si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati inu ãrin igbẹ̀: on si wò, si kiyesi i, iná njó igbẹ́, igbẹ́ na kò si run.
Eks 3:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun. Angẹli OLUWA farahàn án ninu ahọ́n iná láàrin ìgbẹ́; bí ó ti wò ó, ó rí i pé iná ń jó nítòótọ́, ṣugbọn igbó náà kò jóná.
Eks 3:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀ ni angẹli OLúWA ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run