Eks 29:15-30
Eks 29:15-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o si mú àgbo kan; ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori. Iwọ o si pa àgbo na, iwọ o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀, iwọ o si fi i wọ́n pẹpẹ na yiká. Iwọ o si kun àgbo na, iwọ o si fọ̀ ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀, iwọ o si fi wọn lé ara wọn, ati lé ori rẹ̀. Iwọ o si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ na: ẹbọ sisun ni si OLUWA: õrùn didùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. Iwọ o si mú àgbo keji; Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori. Nigbana ni ki iwọ ki o pa àgbo na, ki o si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si eti ọtún awọn ọmọ rẹ̀, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn, ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n pẹpẹ na yiká. Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. Iwọ o si mú ọrá, ati ìru ti o lọrá ti àgbo na, ati ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ̀, ati iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, ati itan ọtún; nitori àgbo ìyasimimọ́ ni: Ati ìṣu àkara kan, ati àkara kan ti a fi oróro din, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan kuro ninu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA: Iwọ o si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni lọwọ, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀; iwọ o si ma fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA. Iwọ o si gbà wọn li ọwọ́ wọn, iwọ o si sun wọn lori pẹpẹ na li ẹbọ sisun, fun õrùn didùn niwaju OLUWA: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. Iwọ o si mú igẹ̀ àgbo ìyasimimọ́ Aaroni, iwọ o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; ìpín tirẹ li eyinì. Iwọ o si yà igẹ̀ ẹbọ fifì na simimọ́, ati itan ẹbọ agbesọsoke, ti a fì, ti a si gbesọsoke ninu àgbo ìyasimimọ́ na, ani ninu eyiti iṣe ti Aaroni, ati ninu eyiti iṣe ti awọn ọmọ rẹ̀: Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA. Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn. Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì.
Eks 29:15-30 Yoruba Bible (YCE)
“Lẹ́yìn náà, mú ọ̀kan ninu àwọn àgbò mejeeji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí. Lẹ́yìn náà, pa àgbò náà, sì gba ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o dà á sí ara pẹpẹ yíká. Gé ẹran àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀. Dà wọ́n mọ́ àwọn tí o gé wẹ́wẹ́ ati orí rẹ̀, kí o sì sun gbogbo wọn lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun olóòórùn dídùn ni sí OLUWA, àní ẹbọ tí a fi iná sun. “Lẹ́yìn náà, mú àgbò keji, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé e lórí. Pa àgbò náà, kí o sì gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kí o tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ati sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn pẹlu. Lẹ́yìn náà, da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ara pẹpẹ yíká. Mú lára ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lára pẹpẹ, sì mú ninu òróró tí wọ́n máa ń ta sí ni lórí, kí o wọ́n ọn sí Aaroni lórí ati sí ara ẹ̀wù rẹ̀, ati sí orí àwọn ọmọ rẹ̀, ati sí ara ẹ̀wù wọn. Òun ati ẹ̀wù rẹ̀ yóo di mímọ́, àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹ̀wù wọn yóo sì di mímọ́ pẹlu. “Mú ọ̀rá àgbò náà ati ìrù rẹ̀ tòun tọ̀rá rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun ati èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀; ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n ati itan rẹ̀ ọ̀tún, nítorí àgbò ìyàsímímọ́ ni. Mú burẹdi kan, àkàrà dídùn kan pẹlu òróró, ati burẹdi pẹlẹbẹ láti inú agbọ̀n burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí ó wà níwájú OLUWA. Kó gbogbo wọn lé Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú OLUWA. Lẹ́yìn náà, gba gbogbo àkàrà náà lọ́wọ́ wọn, kí o fi iná sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹlu ẹbọ sísun olóòórùn dídùn níwájú OLUWA, ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA ni. “Mú igẹ̀ àgbò tí a fi ya Aaroni sí mímọ́, kí o sì fì í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, èyí ni yóo jẹ́ ìpín tìrẹ. “O óo ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́ ati itan tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa lára àgbò ìyàsímímọ́, nítorí pé, ti Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni. Yóo máa jẹ́ ìpín ìran wọn títí lae, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa fún àwọn alufaa lára ẹbọ alaafia wọn; ẹbọ wọn sí OLUWA ni. “Ẹ̀wù mímọ́ Aaroni yóo di ti arọmọdọmọ rẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn aṣọ mímọ́ náà ni wọn yóo máa wọ̀; wọn yóo máa wọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá fi àmì òróró yàn wọ́n, tí wọ́n sì yà wọ́n sí mímọ́. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó bá di alufaa dípò rẹ̀ yóo wọ àwọn aṣọ wọnyi fún ọjọ́ meje, nígbà tí ó bá wá sí ibi àgọ́ àjọ.
Eks 29:15-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì fi wọ́n pẹpẹ náà yíká. Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn. Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí OLúWA, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe sí OLúWA ni. “Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká. Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́. “Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́). Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú OLúWA, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan. Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLúWA. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú OLúWA, ẹbọ ti a fi iná sun sí OLúWA. Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú OLúWA; ìpín tìrẹ ni èyí. “Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí OLúWA láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn. “Aṣọ mímọ́ Aaroni yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́. Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.