Eks 29:1-14

Eks 29:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

EYI si li ohun ti iwọ o ṣe si wọn lati yà wọn simimọ́, lati ma ṣe alufa fun mi: mú ẹgbọ̀rọ akọmalu kan, ati àgbo meji ti kò li abùku. Ati àkara alaiwu, ati adidùn àkara alaiwu ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si lori; iyẹfun alikama ni ki o fi ṣe wọn. Iwọ o si fi wọn sinu agbọ̀n kan, iwọ o si mú wọn wá ninu agbọ̀n na, pẹlu akọmalu na ati àgbo mejeji. Iwọ o si mú Aaroni pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn. Iwọ o si mú aṣọ wọnni, iwọ o si fi ẹ̀wu-awọtẹlẹ nì wọ̀ Aaroni, ati aṣọ igunwa efodi, ati efodi, ati igbàiya, ki o si fi onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi dì i. Iwọ o si fi fila nì dé e li ori, iwọ o si fi adé mimọ́ nì sara fila na. Nigbana ni iwọ o si mú oróro itasori, iwọ o si dà a si i li ori, iwọ o si fi oróro yà a simimọ́. Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá tosi, iwọ o si wọ̀ wọn li ẹ̀wu. Iwọ o si dì wọn li ọjá-amure, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si fi fila dé wọn: iṣẹ-alufa yio si ma jẹ́ ti wọn ni ìlana titi aiye: iwọ o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́. Iwọ o si mú akọmalu na wá siwaju agọ́ ajọ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé akọmalu na li ori. Iwọ o si pa akọmalu na niwaju OLUWA, loju ọ̀na agọ́ ajọ. Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, iwọ o si fi ika rẹ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na; iwọ o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si ìha isalẹ pẹpẹ na. Iwọ o si mú gbogbo ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bori ẹ̀dọ, ati ti iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, iwọ o si sun u lori pẹpẹ na. Ṣugbọn ẹran akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati igbẹ rẹ̀, on ni ki iwọ ki o fi iná sun lẹhin ode ibudó: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

Eks 29:1-14 Yoruba Bible (YCE)

“Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù, mú burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ati àkàrà dídùn tí kò ní ìwúkàrà tí a fi òróró pò, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà, tí a da òróró sí lórí. Ìyẹ̀fun kíkúnná ni kí o fi ṣe wọ́n. Kó àwọn burẹdi ati àkàrà náà sinu agbọ̀n kan, gbé wọn wá pẹlu akọ mààlúù ati àgbò mejeeji náà. “Mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n. Lẹ́yìn náà, kó àwọn aṣọ náà, wọ Aaroni lẹ́wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu, ati efodu náà, ati ìgbàyà. Lẹ́yìn náà, fi ọ̀já efodu tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dì í ní àmùrè. Fi fìlà náà dé e lórí, kí o sì gbé adé mímọ́ lé orí fìlà náà. Gbé òróró ìyàsọ́tọ̀, kí o dà á lé e lórí láti yà á sọ́tọ̀. “Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá, kí o sì wọ̀ wọ́n lẹ́wù, dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi. “Lẹ́yìn náà, mú akọ mààlúù náà wá siwaju àgọ́ àjọ, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ọwọ́ lé akọ mààlúù náà lórí. Lẹ́yìn náà, pa akọ mààlúù náà níwájú OLUWA lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ àjọ. Gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, kí o fi ìka rẹ tọ́ ọ sí ara ìwo pẹpẹ, kí o sì da ìyókù rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Fá gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati ẹ̀dọ̀ akọ mààlúù náà; mú kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n; kí o sun wọ́n lórí pẹpẹ náà. Ṣugbọn lẹ́yìn ibùdó ni kí o ti fi iná sun ẹran ara rẹ̀, ati awọ rẹ̀, ati nǹkan inú rẹ̀, nítorí pé, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Eks 29:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọn lè máa ṣe àlùfáà fún mi: Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù. Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí. Ìwọ yóò sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà. Nígbà náà ni ìwọ yóò mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, àti aṣọ ìgúnwà efodu, àti efodu, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu dì í. Ìwọ yóò sì fi fìlà dé e ní orí, ìwọ yóò sì ṣe adé mímọ́ sára fìlà náà. Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí. Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ tiwọn ní ìlànà títí ayé. “Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́. “Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá síwájú àgọ́ àjọ, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé akọ màlúù ní orí. Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú OLúWA ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ. Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.