Eks 28:2-3
Eks 28:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o si dá aṣọ mimọ́ fun Aaroni arakunrin rẹ fun ogo ati fun ọṣọ́. Iwọ o si sọ fun gbogbo awọn ti o ṣe amoye, awọn ẹniti mo fi ẹmi ọgbọ́n kún, ki nwọn ki o le dá aṣọ Aaroni lati yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
Pín
Kà Eks 28Eks 28:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Sì dá ẹ̀wù mímọ́ kan fún Aaroni, arakunrin rẹ, kí ó lè fún un ní iyì ati ọlá. Pe gbogbo àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ ọnà jọ, àwọn tí mo fi ìmọ̀ ati òye iṣẹ́ ọnà dá lọ́lá, kí wọ́n rán aṣọ alufaa kan fún Aaroni láti yà á sọ́tọ̀ fún mi, gẹ́gẹ́ bí alufaa.
Pín
Kà Eks 28Eks 28:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá. Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Aaroni, fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
Pín
Kà Eks 28