Eks 25:31-40 - Compare All Versions
Eks 25:31-40 YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́: Ẹka mẹfa ni yio yọ ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha keji: Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na. Ati ninu ọpá-fitila na li ago mẹrin yio wà ti a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi wọn ati itanna wọn. Irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, gẹgẹ bi ẹka rẹ̀ mẹfẹfa ti o ti ara ọpá-fitila na yọ jade. Irudi wọn ati ẹka wọn ki o ri bakanna: ki gbogbo rẹ̀ ki o jẹ́ lilù kìki wurà kan. Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀. Ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, kìki wurà ni ki o jẹ́. Talenti kan kìki wurà ni ki o fi ṣe e, pẹlu gbogbo ohunèlo wọnyi. Si kiyesi i, ki iwọ ki o ṣe wọn gẹgẹ bi apẹrẹ wọn, ti a fihàn ọ lori oke.
Eks 25:31-40 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ ó sì ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, ṣe ọ̀pá fìtílà kan, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. Àwo mẹ́ta ni kí a ṣe bí ìtànná almondi, tí ó ṣọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta yóò sì wà ní ẹ̀ka kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà. Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta, ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà. “Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀. Àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alimagaji rẹ̀, kí ó jẹ́ kìkì wúrà. Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí. Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.
Eks 25:31-40 YCE (Yoruba Bible)
“Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan. Ṣe ẹ̀ka mẹfa sára ọ̀pá fìtílà náà, mẹta ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ati mẹta ní ẹ̀gbẹ́ keji. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi. Kí òdòdó aláràbarà mẹrin wà lórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, kí àwọn òdòdó náà dàbí alimọndi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ so, kí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kéékèèké kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó ya lára ọ̀pá fìtílà náà. Àṣepọ̀ ni kí wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà, ati àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ati àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kékeré abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀. Ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n sì fi ṣe gbogbo rẹ̀. Ṣe fìtílà meje fún ọ̀pá fìtílà náà, kí o sì gbé wọn ka orí ọ̀pá náà ní ọ̀nà tí gbogbo wọn yóo fi kọjú siwaju. Ojúlówó wúrà ni kí o fi ṣe ẹnu rẹ̀ ati àwo pẹrẹsẹ rẹ̀, talẹnti wúrà kan ni kí o fi ṣe ọ̀pá fìtílà náà ati gbogbo ohun èlò rẹ̀. Rí i dájú pé o ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè.