Eks 24:1-2
Eks 24:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére. Mose nikanṣoṣo ni yio si sunmọ OLUWA; ṣugbọn awọn wọnyi kò gbọdọ sunmọ tosi; bẹ̃li awọn enia kò gbọdọ bá a gòke lọ.
Eks 24:1-2 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA wí fún Mose pé, “Ẹ gòkè tọ èmi OLUWA wá, ìwọ ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, kí ẹ sì sin èmi OLUWA ní òkèèrè. Ìwọ Mose nìkan ni kí o súnmọ́ mi, kí àwọn yòókù má ṣe súnmọ́ mi, má sì jẹ́ kí àwọn eniyan ba yín gòkè wá rárá.”
Eks 24:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ OLúWA wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin (70) àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré. Ṣùgbọ́n Mose nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ OLúWA; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”