Eks 23:1-9
Eks 23:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
IWỌ kò gbọdọ gbà ìhin eke: máṣe li ọwọ́ si i pẹlu enia buburu lati ṣe ẹlẹri aiṣododo. Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ̀ li ọ̀ran ki o tẹ̀ si ọ̀pọ enia lati yi ẹjọ́ po. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbè talaka li ẹjọ́ rẹ̀. Bi iwọ ba bá akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ọtá rẹ ti o ṣina, ki iwọ ki o mú u pada fun u wá nitõtọ. Bi iwọ ba ri kẹtẹkẹtẹ ẹniti o korira rẹ, ti o dubulẹ labẹ ẹrù rẹ̀, ti iwọ iba yẹra lati bá a tú u, iwọ o bá a tú u nitõtọ. Iwọ kò gbọdọ yi ẹjọ́ talaka rẹ po li ọ̀ran rẹ̀. Takéte li ọ̀ran eke; ati alaiṣẹ ati olododo ni iwọ kò gbọdọ pa: nitoriti emi ki yio dá enia buburu lare. Iwọ kò gbọdọ gbà ọrẹ: nitori ọrẹ ni ifọ́ awọn ti o riran loju, a si yi ọ̀ran awọn olododo po. Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ pọ́n alejò kan loju: ẹnyin sa ti mọ̀ inu alejò, nitoriti ẹnyin ti jẹ́ alejò ni ilẹ Egipti.
Eks 23:1-9 Yoruba Bible (YCE)
“O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké. O kò gbọdọ̀ bá ọ̀pọ̀ eniyan kẹ́gbẹ́ láti ṣe ibi, tabi kí o tẹ̀lé ọ̀pọ̀ eniyan láti jẹ́rìí èké tí ó lè yí ìdájọ́ po. O kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka lórí ẹjọ́ rẹ̀. “Bí o bá pàdé akọ mààlúù ọ̀tá rẹ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ń ṣìnà lọ, o níláti fà á pada wá fún un. Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀. “O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́. O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre. O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi. “O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti.
Eks 23:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké. “Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀. “Bí ìwọ bá ṣe alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ tí ó ṣìnà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un. Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó kórìíra rẹ tí ẹrù ṣubú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo. Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre. “Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. “Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.