Eks 22:21-31

Eks 22:21-31 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú tabi kí ó ni ín lára, nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fìyà jẹ opó tabi aláìníbaba. Bí ẹnikẹ́ni bá fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bá ké pè mí, dájúdájú n óo gbọ́ igbe wọn; ibinu mi yóo sì ru sí yín, n óo fi idà pa yín, àwọn aya yín yóo di opó, àwọn ọmọ yín yóo sì di aláìníbaba. “Bí o bá yá ẹnikẹ́ni lówó ninu àwọn eniyan mi, tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, tí ó ṣe aláìní, má ṣe bí àwọn tí wọn ń fi owó wọn gba èlé, má gba èlé lórí owó tí o yá a. Bí aládùúgbò rẹ bá fi ẹ̀wù rẹ̀ dógò lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì gbà á, dá a pada fún un kí oòrùn tó wọ̀; nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí. “O kò gbọdọ̀ kẹ́gàn Ọlọrun, o kò sì gbọdọ̀ gbé ìjòyè àwọn eniyan rẹ ṣépè. “O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi. “O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu. Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi. “Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún mi, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ òkú ẹran tí ẹranko bá pa ninu ìgbẹ́, ajá ni kí ẹ gbé irú ẹran bẹ́ẹ̀ fún.

Eks 22:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì ni ilẹ̀ Ejibiti rí. “Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ. Bí ìwọ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn. Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba. “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé. Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí oòrùn tó ó wọ̀, Nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sí mi, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi. “Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run tàbí gégùn lé orí ìjòyè àwọn ènìyàn rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi. Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ́ kẹjọ. “Ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mímọ́ mi. Nítorí náà má ṣe jẹ ẹran ti ẹranko búburú fàya: ẹ fi fún ajá jẹ.