Eks 22:2-3
Eks 22:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi a ba ri olè ti nrunlẹ wọle, ti a si lù u ti o kú, a ki yio ta ẹ̀jẹ silẹ fun u. Bi õrùn ba là bá a, a o ta ẹ̀jẹ silẹ fun u; sisan li on iba san; bi kò ni nkan, njẹ a o tà a nitori olè rẹ̀.
Eks 22:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Bí a bá ká olè mọ́ ibi tí ó ti ń fọ́lé lóru, tí a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa kò jẹ̀bi. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ pé lojumọmọ ni, ẹ̀bi wà fún ẹni tí ó lù ú pa. Ṣugbọn tí ọwọ́ bá tẹ olè lojumọmọ, ó níláti san ohun tí ó jí pada.
Eks 22:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà.