Eks 21:7-8
Eks 21:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ. Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
Eks 21:7-8 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin. Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un.
Eks 21:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò nígba òmìnira bí i ti ọmọkùnrin. Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àjèjì, nítorí pé òun ni kò ṣe ojúṣe rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà.