Eks 20:13-17
Eks 20:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ kò gbọdọ pania. Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga. Iwọ kò gbọdọ jale. Iwọ kò gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ. Iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ kò gbọdọ ṣojukokoro si aya ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ̀ obinrin, akọmalu rẹ̀, kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, tabi ohun gbogbo ti iṣe ti ẹnikeji rẹ.
Eks 20:13-17 Yoruba Bible (YCE)
“O kò gbọdọ̀ paniyan. “O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga. “O kò gbọdọ̀ jalè. “O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnikeji rẹ. “O kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ọmọnikeji rẹ, tabi sí aya rẹ̀ tabi sí iranṣẹ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, tabi sí akọ mààlúù rẹ̀, tabi sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi sí ohunkohun tí ó jẹ́ ti ọmọnikeji rẹ.”
Eks 20:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”