Eks 20:1-4
Eks 20:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi pe, Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ jade lati ilẹ Egipti, lati oko-ẹrú jade wá. Iwọ kò gbọdọ lí Ọlọrun miran pẹlu mi. Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ.
Eks 20:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun sì sọ ọ̀rọ̀ wọnyii, ó ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà: “O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. “O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.
Eks 20:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé: “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.