Eks 2:1-22
Eks 2:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌKUNRIN kan ara ile Lefi si lọ, o si fẹ́ ọmọbinrin Lefi kan. Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta. Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na. Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na. Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ si nrìn lọ li ẹba odò na; nigbati o si ri apoti na lãrin koriko odò, o rán ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ kan lati lọ gbé e wá. Nigbati o si ṣi i, o ri ọmọ na; si kiyesi i ọmọde na nsọkun. Inu rẹ̀ si yọ́ si i, o si wipe, Ọkan ninu awọn ọmọ Heberu li eyi. Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ? Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Lọ. Ọmọbinrin na si lọ, o si pè iya ọmọ na wá. Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Gbé ọmọ yi lọ ki o si tọ́ ọ fun mi, emi o si san owo iṣẹ rẹ fun ọ. Obinrin na si gbé ọmọ na lọ, o si tọ́ ọ. Ọmọ na si dàgba, o si mú u tọ̀ ọmọbinrin Farao wá, on si di ọmọ rẹ̀. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Mose, o si wipe, Nitoriti mo fà a jade ninu omi. O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀. O si wò ihin, o wò ọhún, nigbati o si ri pe, kò si ẹnikan, o lù ara Egipti na pa, o si bò o ninu yanrin. Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ? On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀. Nigbati Farao si gbọ́ ọ̀ran yi, o nwá ọ̀na lati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si ngbé ilẹ Midiani: o si joko li ẹba kanga kan. Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn. Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn. Nigbati nwọn si padà dé lati ọdọ Reueli baba wọn, o ni Ẽtiri ti ẹnyin fi tète dé bẹ̃ loni? Nwọn si wipe, Ara Egipti kan li o gbà wa lọwọ awọn oluṣọ-agutan, o si pọn omi to fun wa pẹlu, o si fi fun agbo-ẹran. O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun. O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose. On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti nṣe atipo ni ilẹ ajeji.
Eks 2:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Lefi fẹ́ obinrin kan tí òun náà jẹ́ ẹ̀yà Lefi. Obinrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Nígbà tí ó rí i pé ọmọ náà jẹ́ arẹwà, ó gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta. Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i. Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.” Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?” Ọmọbinrin Farao dá a lóhùn pé, “Lọ pè é wá.” Ọmọbinrin náà bá yára lọ pe ìyá ọmọ náà. Ọmọbinrin Farao sọ fún ìyá ọmọ náà pé, “Gbé ọmọ yìí lọ, kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, n óo sì san owó àgbàtọ́ rẹ̀ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni obinrin náà ṣe gba ọmọ, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó gbé e pada fún ọmọbinrin Farao, ó sì fi ṣe ọmọ, ó sọ ọ́ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí pé láti inú omi ni mo ti fà á jáde.” Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà tí ó wo ọ̀tún, tí ó wo òsì, tí kò rí ẹnìkankan, ó lu ará Ijipti náà pa, ó sì bò ó mọ́ inú yanrìn. Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.” Nígbà tí Farao gbọ́, ó ń wá ọ̀nà àtipa Mose. Ṣugbọn Mose sálọ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó lọ sí ilẹ̀ Midiani, ó sì jókòó lẹ́bàá kànga kan. Àwọn ọmọbinrin meje kan wá pọn omi, wọ́n jẹ́ ọmọ Jẹtiro, alufaa ìlú Midiani. Wọ́n pọn omi kún ọpọ́n ìmumi àwọn ẹran, láti fún àwọn agbo ẹran baba wọn ní omi mu. Nígbà tí àwọn olùṣọ́-aguntan dé, wọ́n lé àwọn ọmọbinrin meje náà sẹ́yìn; ṣugbọn Mose dìde, ó ran àwọn ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ó sì fún àwọn ẹran wọn ní omi mu. Nígbà tí wọ́n pada dé ọ̀dọ̀ Reueli, baba wọn, ó bi wọ́n pé, “Ó ṣe ya yín tó báyìí lónìí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ijipti kan ni ó gbà wá kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan náà, ó tilẹ̀ tún bá wa pọn omi fún agbo ẹran wa.” Reueli bá bi àwọn ọmọ rẹ̀ léèrè pé, “Níbo ni ará Ijipti ọ̀hún wà? Kí ló dé tí ẹ fi sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wọlé, kí ó wá jẹun.” Mose gbà láti máa gbé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà, ó bá fún un ní Sipora, ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ láti fi ṣe aya. Ó bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọmọ náà ní Geriṣomu, ó wí pé, “Mo jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”
Eks 2:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, ọkùnrin ará ilé Lefi kan fẹ́ ọmọbìnrin ará Lefi kan ni ìyàwó. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tí ó rí í pé ọmọ náà rẹwà, ó gbé ọmọ náà pamọ́ fún oṣù mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nígbà tí kò le è gbé e pamọ́ mọ́, ó fi ewé papirusi hun apẹ̀rẹ̀, ó sì fi ọ̀dà àti òjé igi sán apẹ̀rẹ̀ náà. Ó sì tẹ́ ọmọ náà sínú rẹ̀, ó sì gbe é sí inú eèsún ni etí odò Naili. Arábìnrin rẹ̀ dúró ni òkèèrè láti wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà. Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá, ó ṣí i, ó sì rí ọmọ náà. Ọmọ náà ń sọkún, àánú ọmọ náà sì ṣe é. Ó wí pé “Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Heberu ni èyí.” Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá, Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.” Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mose ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Ejibiti tí ń lu ará Heberu, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Ejibiti náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Heberu méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Heberu arákùnrin rẹ?” Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mose, ó sì wí pé, “lóòótọ́ ni ọ̀ràn yìí ti di mí mọ̀.” Nígbà ti Farao sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mose, ṣùgbọ́n Mose sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Farao, ó lọ sí Midiani láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan. Ó sì ṣe, àlùfáà Midiani kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn. Àwọn darandaran kan wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mose dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi. Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Reueli baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Ejibiti kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.” Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.” Mose gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ẹni tí o fi Sippora, ọmọbìnrin rẹ̀ fún Mose láti fi ṣe aya. Ó sì bí ọmọkùnrin kan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Gerṣomu, ó wí pé “Èmi ń ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”