Eks 19:7-8
Eks 19:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si wá o si ranṣẹ pè awọn àgba awọn enia, o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi lelẹ niwaju wọn ti OLUWA palaṣẹ fun u. Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọ̀rọ awọn enia pada tọ̀ OLUWA lọ.
Eks 19:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá pada wá, ó pe àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un fún wọn. Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA.
Eks 19:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti OLúWA pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti OLúWA wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ OLúWA lọ.