Eks 16:4
Eks 16:4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ.
Pín
Kà Eks 16Eks 16:4 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e.
Pín
Kà Eks 16Eks 16:4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.
Pín
Kà Eks 16