Eks 16:19-36

Eks 16:19-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

Mose si wi fun wọn pe, Ki ẹnikan ki o má kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ti Mose; bẹ̃li ẹlomiran si kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, o si di idin, o si rùn; Mose si binu si wọn. Nwọn si nkó o li orowurọ̀, olukuluku bi ijẹ tirẹ̀; nigbati õrùn si mu, o yọ́. O si ṣe ni ijọ́ kẹfa, nwọn kó ìwọn onjẹ ẹrinmeji, omeri meji fun ẹni kọkan: gbogbo awọn olori ijọ na si wá nwọn sọ fun Mose. O si wi fun wọn pe, Eyi na li OLUWA ti wi pe, Ọla li ọjọ́ isimi, isimi mimọ́ fun OLUWA; ẹ yan eyiti ẹnyin ni iyan, ki ẹ si bọ̀ eyiti ẹnyin ni ibọ̀; eyiti o si kù, ẹ fi i silẹ lati pa a mọ́ dé owurọ̀. Nwọn si fi i silẹ titi di owurọ̀, bi Mose ti paṣẹ fun wọn; kò si rùn, bẹ̃ni kò sí idin ninu rẹ̀. Mose si wi pe, Ẹ jẹ eyinì li oni; nitori oni li ọjọ́ isimi fun OLUWA: li oni ẹnyin ki yio ri i ninu igbẹ́. Li ọjọ́ mẹfa li ẹ o ma kó o; ṣugbọn li ọjọ́ keje li ọjọ́ isimi, ninu rẹ̀ ni ki yio si nkan. O si ṣe li ọjọ́ keje awọn kan ninu awọn enia jade lọ ikó, nwọn kò si ri nkan. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẹ o ti kọ̀ lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́ pẹ to? Wò o, OLUWA sa ti fi ọjọ́ isimi fun nyin, nitorina li o ṣe fi onjẹ ijọ́ meji fun nyin li ọjọ́ kẹfa; ki olukuluku ki o joko ni ipò rẹ̀, ki ẹnikẹni ki o máṣe jade kuro ni ipò rẹ̀ li ọjọ́ keje. Bẹ̃li awọn enia na simi li ọjọ́ keje. Awọn ara ile Israeli si pè orukọ rẹ̀ ni Manna; o si dabi irugbìn korianderi, funfun; adùn rẹ̀ si dabi àkara fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe. Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, Ẹ kún òṣuwọn omeri kan ninu rẹ̀ lati pamọ́ fun irandiran nyin; ki nwọn ki o le ma ri onjẹ ti mo fi bọ́ nyin ni ijù, nigbati mo mú nyin jade kuro ni ilẹ Egipti. Mose si wi fun Aaroni pe, Mú ìkoko kan, ki o si fi òṣuwọn omeri kan ti o kún fun manna sinu rẹ̀, ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA, lati pa a mọ́ fun irandiran nyin. Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li Aaroni gbé e kalẹ niwaju ibi Ẹrí lati pa a mọ́. Awọn ọmọ Israeli si jẹ manna li ogoji ọdún, titi nwọn fi dé ilẹ ti a tẹ̀dó; nwọn jẹ manna titi nwọn fi dé àgbegbe ilẹ Kenaani. Njẹ òṣuwọn omeri kan ni idamẹwa efa.

Eks 16:19-36 Yoruba Bible (YCE)

Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.” Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn. Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose, ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ” Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.” Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun. OLUWA bá wí fún Mose pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi kọ̀ láti pa àṣẹ ati òfin mi mọ́. Ẹ wò ó! OLUWA ti fún yín ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé, ní ọjọ́ kẹfa ó fún yín ní oúnjẹ fún ọjọ́ meji, kí olukuluku lè dúró sí ààyè rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde ní ilé rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” Àwọn eniyan náà bá sinmi ní ọjọ́ keje. Àwọn eniyan Israẹli pe orúkọ oúnjẹ náà ní mana, ó rí rínbíntín-rínbíntín, ó dàbí èso igi korianda, ó funfun, ó sì dùn lẹ́nu bíi burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi oyin ṣe. Mose wí fún wọn pé, “Àṣẹ tí OLUWA pa nìyí: ‘Ẹ fi ìwọ̀n omeri kan pamọ́ láti ìrandíran yín, kí àwọn ọmọ yín lè rí irú oúnjẹ tí mo fi bọ́ yín ninu aṣálẹ̀ nígbà tí mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.’ ” Mose bá sọ fún Aaroni pé, “Mú ìkòkò kan kí o fi ìwọ̀n omeri mana kan sinu rẹ̀, kí o gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA, kí ẹ pa á mọ́ láti ìrandíran yín.” Aaroni bá gbé e kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA ti pa fún Mose. Àwọn eniyan Israẹli jẹ mana náà fún ogoji ọdún, títí wọ́n fi dé ilẹ̀ tí wọ́n lè máa gbé, òun ni wọ́n jẹ títí tí wọ́n fi dé etí ilẹ̀ Kenaani. Ìwọ̀n omeri kan jẹ́ ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa kan.

Eks 16:19-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Mose sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.” Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose, wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn. Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí oòrùn bá sì mú, a sì yọ́. Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń kó tẹ́lẹ̀: òsùwọ̀n omeri méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mose. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún OLúWA. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ” Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin. Mose sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi OLúWA. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní. Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.” Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́? Wò ó? OLúWA ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje. Àwọn ènìyàn Israẹli sì pe oúnjẹ náà ní manna. Ó funfun bí irúgbìn korianderi, ó sì dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a fi oyin ṣe. Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ, ‘Ẹ mú òsùwọ̀n omeri manna kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Ejibiti.’ ” Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó manna tí ó kún òsùwọ̀n omeri kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú OLúWA láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.” Bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose, Aaroni gbé manna sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́. Àwọn ará Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kenaani ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ, wọ́n jẹ manna títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbègbè Kenaani. (Òsùwọ̀n omeri kan sì jẹ́ ìdákan nínú ìdámẹ́wàá efa.)