Eks 16:1-4
Eks 16:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti. Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na: Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi. Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ.
Eks 16:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli jáde kúrò ní Elimu, wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini tí ó wà ní ààrin Elimu ati Sinai, ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keji tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ náà. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e.
Eks 16:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìjọ àwọn ọmọ Israẹli mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Elimu, wọ́n dé sí ijù Sini tí ó wà láàrín Elimu àti Sinai, ni ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà. Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ OLúWA kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.