Eks 16:1-12
Eks 16:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
NWỌN si ṣí lati Elimu, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si dé ijù Sini, ti o wà li agbedemeji Elimu on Sinai, ni ijọ́ kẹdogun oṣù keji, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni ilẹ Egipti. Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni ni ijù na: Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi. Nigbana li OLUWA sọ fun Mose pe, Kiyesi i, emi o rọ̀jo onjẹ fun nyin lati ọrun wá; awọn enia yio si ma jade lọ ikó ìwọn ti õjọ li ojojumọ́, ki emi ki o le dan wọn wò, bi nwọn o fẹ́ lati ma rìn nipa ofin mi, bi bẹ̃kọ. Yio si ṣe, li ọjọ́ kẹfa, nwọn o si pèse eyiti nwọn múwa; yio si to ìwọn meji eyiti nwọn ima kó li ojojumọ́. Mose ati Aaroni si wi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli pe, Li aṣalẹ, li ẹnyin o si mọ̀ pe, OLUWA li o mú nyin jade lati Egipti wá: Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa? Mose si wi pe, Bayi ni yio ri nigbati OLUWA yio fun nyin li ẹran jẹ li aṣalẹ, ati onjẹ ajẹyo li owurọ̀; nitoriti OLUWA gbọ́ kikùn nyin ti ẹnyin kùn si i: ta si li awa? kikùn nyin ki iṣe si wa, bikoṣe si OLUWA. Mose si sọ fun Aaroni pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ iwaju OLUWA, nitoriti o ti gbọ́ kikùn nyin. O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na. OLUWA si sọ fun Mose pe, Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli: sọ fun wọn pe, Li aṣalẹ ẹnyin o jẹ ẹran, ati li owurọ̀ a o si fi onjẹ kún nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Eks 16:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli jáde kúrò ní Elimu, wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini tí ó wà ní ààrin Elimu ati Sinai, ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keji tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ náà. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀, wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹfa, kí wọ́n kó oúnjẹ wálé kí ó tó ìlọ́po meji èyí tí wọn ń kó ní ojoojumọ.” Mose ati Aaroni bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́ òní ni ẹ óo mọ̀ pé OLUWA ló mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ óo rí ògo OLUWA, nítorí ó ti gbọ́ kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i. Kí ni àwa yìí jẹ́, tí ẹ óo fi máa kùn sí wa?” Mose ní, “OLUWA tìkararẹ̀ ni yóo fún yín ní ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ati burẹdi ní òwúrọ̀. Ẹ óo jẹ àjẹyó, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i; nítorí pé kí ni àwa yìí jẹ́? Gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn, àwa kọ́ ni ẹ̀ ń kùn sí, OLUWA gan-an ni ẹ̀ ń kùn sí.” Mose sọ fún Aaroni pé, “Sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, kí wọ́n súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ OLUWA, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn wọn.” Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu. OLUWA bá wí fún Mose pé, “Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn, wí fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ óo máa jẹ ẹran, ní òwúrọ̀, ẹ óo máa jẹ burẹdi ní àjẹyó. Nígbà náà ni ẹ óo tó mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.’ ”
Eks 16:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìjọ àwọn ọmọ Israẹli mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Elimu, wọ́n dé sí ijù Sini tí ó wà láàrín Elimu àti Sinai, ni ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà. Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ OLúWA kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.” Mose àti Aaroni sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé OLúWA ni ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá. Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo OLúWA, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?” Mose tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé OLúWA ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ́ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkùn ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, OLúWA ni ẹ̀yin kùn sí i.” Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pe, ‘Ẹ wá sí iwájú OLúWA, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ” Ó sì ṣe bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, wọn si bojú wo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo OLúWA si farahàn ni àwọsánmọ̀. OLúWA sọ fún Mose pé, “Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.’ ”