Eks 15:1-5
Eks 15:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke. Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀. Kẹkẹ́ Farao ati ogun rẹ̀ li o mu wọ̀ inu okun: awọn ãyo olori ogun rẹ̀ li o si rì ninu Okun Pupa. Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta.
Eks 15:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA, nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo. Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi, n óo máa yìn ín. Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi; n óo máa gbé e ga. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀. Ó da kẹ̀kẹ́ ogun Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sinu òkun, ó sì ri àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀ sinu Òkun Pupa. Ìkún omi bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n rilẹ̀ sinu ibú omi bí òkúta.
Eks 15:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLúWA: Èmi yóò kọrin sí OLúWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun. OLúWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. Ológun ni OLúWA, OLúWA ni orúkọ rẹ, Kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun pupa. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi Òkun bí òkúta.