Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Eks 15:1-3

Eks 15:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun. OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke. Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀.

Pín
Kà Eks 15

Eks 15:1-3 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Mose ati àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLUWA, wọ́n ní: “N óo kọrin sí OLUWA, nítorí pé, ó ti ja àjàṣẹ́gun tí ó lógo. Àtẹṣin, àtẹni tí ń gùn ún ni ó dà sinu Òkun Pupa. OLUWA ni agbára ati orin mi, ó ti gbà mí là, òun ni Ọlọrun mi, n óo máa yìn ín. Òun ni Ọlọrun àwọn baba ńlá mi; n óo máa gbé e ga. Jagunjagun ni OLUWA, OLUWA sì ni orúkọ rẹ̀.

Pín
Kà Eks 15

Eks 15:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí OLúWA: Èmi yóò kọrin sí OLúWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun. OLúWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. Ológun ni OLúWA, OLúWA ni orúkọ rẹ

Pín
Kà Eks 15
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò