Eks 14:10-18

Eks 14:10-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA. Nwọn si wi fun Mose pe, Nitoriti isà kò sí ni Egipti, ki iwọ ṣe mú wa wá lati kú ni ijù? ẽṣe ti iwọ fi ṣe wa bẹ̃, lati mú wa jade ti Egipti wá? Ọrọ yi ki awa ti sọ fun ọ ni Egipti pe, Jọwọ wa jẹ ki awa ki o ma sìn awọn ara Egipti? O sá san fun wa lati ma sin awọn ara Egipti, jù ki awa kú li aginjù lọ. Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri ìgbala OLUWA, ti yio fihàn nyin li oni: nitori awọn ara Egipti ti ẹnyin ri li oni yi, ẹnyin ki yio si tun ri wọn mọ́ lailai. Nitoriti OLUWA yio jà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pa ẹnu nyin mọ́. OLUWA si wi fun Mose pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkepè mi? sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o tẹ̀ siwaju: Ṣugbọn iwọ gbé ọpá rẹ soke, ki iwọ ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju okun ki o si yà a meji: awọn ọmọ Israeli yio si là ãrin okun na kọja ni iyangbẹ ilẹ. Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀. Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba gbà ogo lori Farao, lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀.

Eks 14:10-18 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti? Ṣebí a sọ fún ọ ní Ijipti pé kí o fi wá sílẹ̀ kí á máa sin àwọn ará Ijipti tí à ń sìn, nítorí pé kì bá sàn kí á máa sin àwọn ará Ijipti ju kí á wá kú sinu aṣálẹ̀ lọ.” Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn, ó ní, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró gbọningbọnin, kí ẹ wá máa wo ohun tí OLUWA yóo ṣe. Ẹ óo rí i bí yóo ṣe gbà yín là lónìí; nítorí pé àwọn ará Ijipti tí ẹ̀ ń wò yìí, ẹ kò tún ní rí wọn mọ́ laelae. OLUWA yóo jà fún yín, ẹ̀yin ẹ ṣá dúró jẹ́.” OLUWA wí fún Mose pé, “Kí ló dé tí o fi ń ké pè mí, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n tẹ̀síwájú. Gbé ọ̀pá rẹ sókè kí o na ọwọ́ sórí Òkun Pupa, kí ó sì pín in sí meji, kí àwọn eniyan Israẹli lè kọjá láàrin rẹ̀ lórí ìyàngbẹ ilẹ̀. N óo mú kí ọkàn àwọn ará Ijipti le, kí wọ́n sì tẹ̀lé àwọn ọmọ Israẹli wọ inú Òkun Pupa, n óo sì gba ògo lórí Farao ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá gba ògo lórí Farao ati kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”

Eks 14:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí Farao ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Ejibiti tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Israẹli, wọ́n kígbe sókè sí OLúWA. Wọ́n sọ fún Mose pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Ejibiti ní ìwọ ṣe mú wa wá láti kú sínú aginjù? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti wá? Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Ejibiti, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Ejibiti’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Ejibiti ju kí a kú sínú aginjù yìí lọ!” Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí OLúWA yóò fi fún un yín lónìí; Àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́. OLúWA yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Israẹli kí wọn máa tẹ̀síwájú. Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi Òkun, kí ó lè pín ní yà kí àwọn ọmọ Israẹli lè la Òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀. Nígbà náà ni èmi yóò sé ọkàn àwọn ará Ejibiti le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Farao; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́ ogun àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀. Àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Farao: lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.”