Eks 13:8-9
Eks 13:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o si sọ fun ọmọ rẹ li ọjọ́ na pe, A nṣe eyi nitori eyiti OLUWA ṣe fun mi nigbati mo jade kuro ni Egipti. Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti.
Eks 13:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Kí olukuluku wí fún ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, ‘Nítorí ohun tí OLUWA ṣe fún mi, nígbà tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí.’ Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.
Eks 13:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí OLúWA ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ Ṣíṣe èyí yóò wà fún ààmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ààmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin OLúWA ní ẹnu rẹ. Nítorí OLúWA mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.