Eks 13:3-5
Eks 13:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ ranti ọjọ́ oni, ninu eyiti ẹnyin jade kuro ni Egipti, kuro li oko-ẹrú; nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú nyin jade kuro nihin: a ki yio si jẹ àkara wiwu. Li ọjọ́ oni li ẹnyin jade li oṣù Abibu. Yio si ṣe nigbati OLUWA yio mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn enia Hitti, ati ti awọn ara Amori, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, on ni iwọ o ma sìn ìsin yi li oṣù yi.
Eks 13:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí. Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu. Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun.
Eks 13:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí OLúWA mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.