Eks 13:17-18
Eks 13:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati Farao jẹ ki awọn enia na ki o lọ tán, Ọlọrun kò si mú wọn tọ̀ ọ̀na ilẹ awọn ara Filistia, eyi li o sa yá; nitoriti Ọlọrun wipe, Ki awọn enia má ba yi ọkàn pada nigbati nwọn ba ri ogun, ki nwọn si pada lọ si Egipti. Ṣugbọn Ọlọrun mu wọn yi lọ li ọ̀na ijù Okun Pupa: awọn ọmọ Israeli jade lọ kuro ni ilẹ Egipti ni ihamọra.
Eks 13:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Farao gbà pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa lọ, Ọlọrun kò mú wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn ará Filistia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ibẹ̀ yá, nítorí pé Ọlọrun rò ó ninu ara rẹ̀ pé, “Kí àwọn eniyan yìí má lọ yí ọkàn pada, bí àwọn kan bá gbógun tì wọ́n lójú ọ̀nà, kí wọ́n sì sá pada sí ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun.
Eks 13:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun.