Eks 13:1-22
Eks 13:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe. Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ ranti ọjọ́ oni, ninu eyiti ẹnyin jade kuro ni Egipti, kuro li oko-ẹrú; nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú nyin jade kuro nihin: a ki yio si jẹ àkara wiwu. Li ọjọ́ oni li ẹnyin jade li oṣù Abibu. Yio si ṣe nigbati OLUWA yio mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn enia Hitti, ati ti awọn ara Amori, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, on ni iwọ o ma sìn ìsin yi li oṣù yi. Ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, li ọjọ́ keje li ajọ yio wà fun OLUWA. Ọjọ́ meje li a o fi jẹ àkara alaiwu; ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ, bẹ̃ni ki a má si ṣe ri iwukàra lọdọ rẹ ni gbogbo ẹkùn rẹ. Iwọ o si sọ fun ọmọ rẹ li ọjọ́ na pe, A nṣe eyi nitori eyiti OLUWA ṣe fun mi nigbati mo jade kuro ni Egipti. Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti. Nitorina ni ki iwọ ki o ma kiyesi ìlana yi li akokò rẹ̀ li ọdọdún. Yio si ṣe nigbati OLUWA ba mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, bi o ti bura fun ọ, ati fun awọn baba rẹ, ti yio si fi fun ọ. Ni iwọ o si yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun OLUWA, ati gbogbo akọ́bi ẹran ti iwọ ni; ti OLUWA li awọn akọ. Ati gbogbo akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada; bi iwọ kò ba rà a pada, njẹ ki iwọ ki o sẹ ẹ li ọrùn: ati gbogbo akọ́bi enia ninu awọn ọmọ ọkunrin rẹ ni iwọ o rapada. Yio si ṣe nigbati ọmọ rẹ yio bère lọwọ rẹ lẹhin-ọla pe, Kili eyi? ki iwọ ki o wi fun u pe, Ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni ilẹ Egipti, kuro li oko-ẹrú: O si ṣe, nigbati Farao kọ̀ lati jẹ ki a lọ, on li OLUWA pa gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ati akọ́bi enia, ati akọ́bi ẹran; nitorina ni mo ṣe fi gbogbo akọ́bi ti iṣe akọ rubọ si OLUWA; ṣugbọn gbogbo awọn akọ́bi ọmọ ọkunrin mi ni mo rapada. Yio si ma ṣe àmi li ọwọ́ rẹ, ati ọjá-igbaju lagbedemeji oju rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú wa jade kuro ni Egipti. O si ṣe, nigbati Farao jẹ ki awọn enia na ki o lọ tán, Ọlọrun kò si mú wọn tọ̀ ọ̀na ilẹ awọn ara Filistia, eyi li o sa yá; nitoriti Ọlọrun wipe, Ki awọn enia má ba yi ọkàn pada nigbati nwọn ba ri ogun, ki nwọn si pada lọ si Egipti. Ṣugbọn Ọlọrun mu wọn yi lọ li ọ̀na ijù Okun Pupa: awọn ọmọ Israeli jade lọ kuro ni ilẹ Egipti ni ihamọra. Mose si gbé egungun Josefu lọ pẹlu rẹ̀; nitori ibura lile li o mu awọn ọmọ Israeli bu pe, Lõtọ li Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò; ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lọ pẹlu nyin kuro nihin. Nwọn si mu ọ̀na-àjo wọn pọ̀n lati Sukkoti lọ, nwọn si dó si Etamu leti ijù. OLUWA si nlọ niwaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma li ọsán, lati ma ṣe amọna fun wọn; ati li oru li ọwọ̀n iná lati ma fi imọlẹ fun wọn; lati ma rìn li ọsán ati li oru. Ọwọ̀n awọsanma na kò kuro li ọsán, tabi ọwọ̀n iná li oru, niwaju awọn enia na.
Eks 13:1-22 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Ya gbogbo àwọn àkọ́bí sí mímọ́ fún mi, ohunkohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn eniyan Israẹli, kì báà ṣe ti eniyan, tabi ti ẹranko, tèmi ni wọ́n.” Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ranti ọjọ́ òní tíí ṣe ọjọ́ tí ẹ jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti inú ìgbèkùn, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mu yín jáde kúrò níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí wọ́n fi ìwúkàrà sí. Òní ni ọjọ́ pé tí ẹ óo jáde kúrò ní Ijipti, ninu oṣù Abibu. Nígbà tí Ọlọrun bá mu yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí ó ti búra fún àwọn baba yín pé òun yóo fi fún yín, tí ó kún fún wàrà ati oyin, ẹ óo máa ṣe ìsìn yìí ninu oṣù yìí lọdọọdun. Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, ní ọjọ́ keje ẹ óo pe àpèjọ kan fún OLUWA láti ṣe àjọ̀dún. Láàrin ọjọ́ meje tí ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, a kò gbọdọ̀ rí burẹdi tí ó ní ìwúkàrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni ninu yín, kò sì gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ní gbogbo agbègbè yín. Kí olukuluku wí fún ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, ‘Nítorí ohun tí OLUWA ṣe fún mi, nígbà tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá, ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí.’ Kí ó jẹ́ àmì ní ọwọ́ rẹ, ati ohun ìrántí láàrin ojú rẹ, kí òfin OLUWA lè wà ní ẹnu rẹ, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá. Nítorí náà, ẹ máa ṣe ìrántí ìlànà yìí ní àkókò rẹ̀ ní ọdọọdún. “Nígbà tí OLUWA bá mu yín dé ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ẹ̀yin ati àwọn baba yín, tí ó bá sì fún yín ní ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí ni ẹ gbọdọ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA. Gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn yín tí ó bá jẹ́ akọ, ti OLUWA ni. Ẹ gbọdọ̀ fi ọ̀dọ́ aguntan ra gbogbo àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín pada, bí ẹ kò bá sì fẹ́ rà wọ́n pada, dandan ni pé kí ẹ lọ́ wọn lọ́rùn pa. Ẹ gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí yín tí wọ́n jẹ́ ọkunrin pada. Ní ọjọ́ iwájú bí àwọn ọmọkunrin yín bá bèèrè ìtumọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́ yín, ohun tí ẹ óo wí fún wọn ni pé, ‘Pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, níbi tí a ti wà ní ìgbèkùn rí. Nítorí pé nígbà tí Farao ṣe orí kunkun, tí ó sì kọ̀, tí kò jẹ́ kí á lọ, OLUWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti, ti eniyan ati ti ẹranko. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi àkọ́bí ẹran ọ̀sìn mi, tí ó bá jẹ́ akọ rúbọ sí OLUWA, tí mo sì fi ń ra àwọn àkọ́bí mi ọkunrin pada.’ Ẹ fi ṣe àmì sí ọwọ́ yín, ati ìgbàjú sí iwájú yín, nítorí pé pẹlu ipá ni OLUWA fi mú wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.” Nígbà tí Farao gbà pé kí àwọn ọmọ Israẹli máa lọ, Ọlọrun kò mú wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn ará Filistia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ibẹ̀ yá, nítorí pé Ọlọrun rò ó ninu ara rẹ̀ pé, “Kí àwọn eniyan yìí má lọ yí ọkàn pada, bí àwọn kan bá gbógun tì wọ́n lójú ọ̀nà, kí wọ́n sì sá pada sí ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun. Mose kó egungun Josẹfu lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń lọ, nítorí pé Josẹfu ti mú kí àwọn ọmọ Israẹli jẹ́jẹ̀ẹ́, ó ní, “Ọlọrun yóo gbà yín là, nígbà tí ó bá yá tí ẹ̀ bá ń lọ, ẹ kó egungun mi lọ́wọ́ lọ.” Wọ́n gbéra láti Sukotu, wọ́n pàgọ́ sí Etamu létí aṣálẹ̀. OLUWA sì ń lọ níwájú wọn ní ọ̀sán ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu láti máa fi ọ̀nà hàn wọ́n, ati ní òru, ninu ọ̀wọ̀n iná láti máa fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa rìn ní ọ̀sán ati ní òru. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu kò fi ìgbà kan kúrò níwájú àwọn eniyan náà ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀wọ̀n iná ní òru.
Eks 13:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.” Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí OLúWA mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. Ní ìgbà tí Ọlọ́run mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún OLúWA. Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí OLúWA ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’ Ṣíṣe èyí yóò wà fún ààmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí ààmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin OLúWA ní ẹnu rẹ. Nítorí OLúWA mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀. Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún. “Lẹ́yìn tí OLúWA tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀, Ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún OLúWA. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti OLúWA. Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà. “Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní OLúWA fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú. Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, OLúWA pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí OLúWA láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’ Èyí yóò sì jẹ́ ààmì ni ọwọ́ yín àti ààmì ní iwájú orí yín pé OLúWA mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.” Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun. Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.” Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù. OLúWA sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru. Ìkùùkuu náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀wọ̀n iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.