Eks 12:29-32
Eks 12:29-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin. Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú. O si pè Mose on Aaroni li oru, o si wipe, Ẹ dide, ki ẹ jade lọ kuro lãrin awọn enia mi, ati ẹnyin ati awọn ọmọ Israeli; ki ẹ si lọ sìn OLUWA, bi ẹ ti wi. Ẹ si mú agbo nyin ati ọwọ́-ẹran nyin, bi ẹ ti wi, ki ẹ si ma lọ; ki ẹ si sure fun mi pẹlu.
Eks 12:29-32 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú. Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni ní òru ọjọ́ náà, ó ní, “Ẹ gbéra, ẹ máa lọ, ẹ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan mi, ati ẹ̀yin ati àwọn eniyan Israẹli, ẹ lọ sin OLUWA yín bí ẹ ti wí. Ẹ máa kó àwọn agbo mààlúù yín lọ, ati agbo aguntan yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ máa lọ; ṣugbọn ẹ súre fún èmi náà!”
Eks 12:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọ̀gànjọ́ òru OLúWA kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, láti orí àkọ́bí. Farao tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú túbú àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú. Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Ejibiti dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú. Farao sì ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni ní òru, ó sì wí pé, “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin àti àwọn ènìyàn Israẹli! Ẹ lọ láti sin OLúWA gẹ́gẹ́ bí ẹ ti béèrè. Ẹ kó agbo àgùntàn yín àti agbo màlúù yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti sọ, kí ẹ sì máa lọ, kí ẹ sì súre fún mi.”