Eks 11:1-3
Eks 11:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o tun mú iyọnu kan wá sara Farao, ati sara Egipti; lẹhin eyinì ni on o jọwọ nyin lọwọ lọ lati ihin: nigbati on o jẹ ki ẹ lọ, àtitán ni yio tì nyin jade nihin. Wi nisisiyi li eti awọn enia wọnyi, ki olukuluku ọkunrin ki o bère lọdọ aladugbo rẹ̀ ati olukuluku obinrin lọdọ aladugbo rẹ̀, ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà. OLUWA si fi ojurere fun awọn enia na li oju awọn ara Egipti. Pẹlupẹlu Mose ọkunrin nì o pọ̀ gidigidi ni ilẹ Egipti, li oju awọn iranṣẹ Farao, ati li oju awọn enia na.
Eks 11:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ, ati ọkunrin ati obinrin wọn, kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà.” OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki.
Eks 11:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, OLúWA sọ fún Mose pé èmi yóò mú ààrùn kan sí i wá sí orí Farao àti ilẹ̀ Ejibiti. Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yin kí ó lọ kúrò níhìn-ín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá. Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀. (OLúWA jẹ́ kí wọn rí ojúrere àwọn ará Ejibiti, pàápàá, Mose fúnrarẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Ejibiti ní iwájú àwọn ìjòyè Farao àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú).