Eks 1:1-8
Eks 1:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀. Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah; Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri. Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti. Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na. Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn. Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu.
Eks 1:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu wá sí Ijipti nìwọ̀nyí, olukuluku pẹlu ìdílé rẹ̀: Reubẹni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Bẹnjamini, Dani, Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Gbogbo àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Jakọbu jẹ́ aadọrin, Josẹfu ti wà ní Ijipti ní tirẹ̀. Nígbà tí ó yá, Josẹfu kú, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ náà kú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí tí gbogbo ìran náà fi kú tán. Ṣugbọn àwọn arọmọdọmọ Israẹli pọ̀ sí i, wọ́n di alágbára gidigidi, wọ́n sì pọ̀ káàkiri ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ó yá, ọba titun kan tí kò mọ Josẹfu gorí oyè, ní ilẹ̀ Ijipti.
Eks 1:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ejibiti, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀: Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda; Isakari, Sebuluni àti Benjamini; Dani àti Naftali; Gadi àti Aṣeri. Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti. Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà. Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti.