Est 8:3-8 - Compare All Versions

Est 8:3-8 YBCV (Bibeli Mimọ)

Esteri si tun sọ niwaju ọba, o wolẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀, o si fi omijé bẹ̀ ẹ pe, ki o mu buburu Hamani, ara Agagi kuro, ati ete ti o ti pa si awọn Ju. Nigbana ni ọba nà ọpá-alade wura si Esteri. Bẹ̃ni Esteri dide, o si duro niwaju ọba. O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba. Nitori pe, emi ti ṣe le ri ibi ti yio wá ba awọn enia mi? tabi emi ti ṣe le ri iparun awọn ibatan mi? Nigbana ni Ahaswerusi ọba wi fun Esteri ayaba, ati fun Mordekai ara Juda na pe, Sa wò o, emi ti fi ile Hamani fun Esteri; on ni nwọn si ti so rọ̀ lori igi, nitoripe o ti gbe ọwọ le awọn Ju. Ẹnyin kọwe ẹ̀wẹ li orukọ ọba, nitori awọn Ju bi ẹnyin ti fẹ́, ki ẹ si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀: nitori iwe ti a ba fi orukọ ọba kọ, ti a ba si fi òruka ọba ṣe edidi, ẹnikan kò le yi i pada.

Est 8:3-8 YCE (Yoruba Bible)

Ẹsita tún bẹ ọba, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pẹlu omijé, pé kí ọba yí ète burúkú tí Hamani, ará Agagi, pa láti run àwọn Juu pada. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹsita. Ó dìde, ó sì dúró níwájú ọba, ó ní, “Bí inú kabiyesi bá dùn sí mi, tí mo sì rí ojurere rẹ̀, bí ó bá fẹ́ràn mi, tí ọ̀rọ̀ náà bá tọ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí ìwé àṣẹ kan ti ọ̀dọ̀ ọba jáde, láti yí ète burúkú tí Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, pa pada, àní ète tí ó pa láti run gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní ìjọba rẹ̀. Mo ṣe lè rí jamba tí ń bọ̀, tabi ìparun tí ń bọ̀ sórí àwọn eniyan mi, kí n sì dákẹ́?” Ahasu-erusi ọba dá Ẹsita Ayaba ati Modekai Juu lóhùn pé, “Mo ti so Hamani kọ́ sórí igi, nítorí ète tí ó pa lórí àwọn Juu, mo sì ti fún Ẹsita ní ilé rẹ̀. Kọ ohunkohun tí ó bá wù ọ́ nípa àwọn Juu ní orúkọ ọba, kí o sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Nítorí pé òfin tí a bá kọ ní orúkọ ọba, tí ó sì ní èdìdì ọba, ẹnikẹ́ni kò lè yí i pada mọ́.”

Est 8:3-8 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀. Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run. Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdílé mi?” Ọba Ahaswerusi dá Esteri ayaba àti Mordekai ará a Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hamani kọlu àwọn ará a Júù, èmi ti fi ilé e rẹ̀ fún Esteri, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi. Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dì í, nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà.”