Est 7:7-10
Est 7:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on. Nigbana ni ọba pẹhinda lati inu àgbala ãfin sinu ibiti nwọn ti nmu ọti-waini, Hamani si ṣubu le ibi ìrọgbọkú lori eyi ti Esteri joko; nigbana ni ọba wi pe, yio ha tẹ́ ayaba lọdọ mi ninu ile bi? Bi ọ̀rọ na ti ti ẹnu ọba jade, nwọn bò oju Hamani. Harbona ọkan ninu awọn ìwẹfa si wi niwaju ọba pe, Sa wò o, igi ti o ga ni ãdọta igbọnwọ ti Hamani ti rì nitori Mordekai ti o ti sọ ọ̀rọ rere fun ọba, o wà li oró ni ile Hamani. Ọba si wi pe, Ẹ so o rọ̀ lori rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn so Hamani rọ̀ sori igi ti o ti rì fun Mordekai; ibinu ọba si rọ̀.
Est 7:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ọba dìde kúrò ní ibi àsè náà pẹlu ibinu, ó jáde lọ sinu àgbàlá ààfin. Nígbà tí Hamani rí i pé ọba ti pinnu ibi fún òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹsita Ayaba fún ẹ̀mí rẹ̀. Bí ọba ti pada wá láti inú àgbàlá sí ibi tí wọ́n ti ń mu ọtí, ó rí Hamani tí ó ṣubú sí ibi àga tí Ẹsita rọ̀gbọ̀kú sí. Ọba ní, “Ṣé yóo tún máa fi ọwọ́ pa Ayaba lára lójú mi ni, ninu ilé mi?” Ní kété tí ọba sọ̀rọ̀ yìí tán, wọ́n faṣọ bo Hamani lójú. Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.” Ọba bá ní kí wọ́n lọ gbé Hamani kọ́ sí orí rẹ̀. Wọ́n bá gbé Hamani kọ́ sí orí igi tí ó ti rì mọ́lẹ̀ fún Modekai, nígbà náà ni inú ọba tó rọ̀.
Est 7:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hamani, ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Esteri ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀. Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì. Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?” Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú. Nígbà náà Harbona ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà marunlélaadọrin ni Hamani ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilé e rẹ̀. Ó ṣe é fún Mordekai, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.” Ọba wí pé, ẹ so ó rọ̀ sórí i rẹ́! Wọ́n sì so Hamani sórí igi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún Mordekai, ìbínú ọba sì rọ̀.