Est 5:14
Est 5:14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Sereṣi aya rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ wi fun u pe, Jẹ ki a rì igi kan, ki o ga ni ãdọta igbọnwọ, ati li ọla ni ki o ba ọba sọ ọ ki a so Mordekai rọ̀ nibẹ: iwọ̀ o si fi ayọ̀ ba ọba lọ si ibi àse. Nkan yi dùn mọ Hamani, o si rì igi na.
Est 5:14 Yoruba Bible (YCE)
Sereṣi iyawo rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un, pé, “Lọ ri igi tí wọn ń gbé eniyan kọ́, kí ó ga ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, sọ fún ọba pé kí ó so Modekai kọ́ sí orí igi náà. Nígbà náà inú rẹ yóo dùn láti lọ sí ibi àsè náà.” Inú Hamani dùn sí ìmọ̀ràn yìí, ó lọ ri igi náà mọ́lẹ̀.
Est 5:14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìyàwó rẹ̀ Sereṣi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ bàtà márùn-ún le láàdọ́rin, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Mordekai rọ̀ sórí i rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àsè pẹ̀lú ayọ̀.” Èrò yí dùn mọ́ Hamani nínú, ó sì ri igi náà.