Est 4:8
Est 4:8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati pẹlu, o fi iwe aṣẹ na pãpã, ti a pa ni Ṣuṣani lati pa awọn Ju run, le e lọwọ, lati fi hàn Esteri, ati lati sọ fun u, ati lati paṣẹ fun u ki on ki o wọle tọ̀ ọba lọ, lati bẹ̀bẹ lọwọ rẹ̀, ati lati bẹ̀bẹ niwaju rẹ̀, nitori awọn enia rẹ̀.
Pín
Kà Est 4Est 4:8 Yoruba Bible (YCE)
Modekai fún Hataki ní ìwé òfin tí wọ́n ṣe ní Susa láti pa gbogbo àwọn Juu run patapata, pé kí ó fi ìwé náà han Ẹsita, kí ó sì là á yé e, kí ó lè lọ siwaju ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀.
Pín
Kà Est 4Est 4:8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun wọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Susa, láti fihan Esteri kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún un, ó sì sọ fún un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ síwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀.
Pín
Kà Est 4