Est 4:1-2
Est 4:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Mordekai mọ̀ gbogbo ohun ti a ṣe, Mordekai fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ-ọ̀fọ on ẽru bò ara, o si jade lọ si ãrin ilu na, o si sọkun kikan ati kikoro. O tilẹ wá siwaju ẹnu-ọna ile ọba: nitori kò si ẹnikan ti o fi aṣọ-ọfọ si ara ti o gbọdọ wọ̀ ẹnu-ọ̀na ile ọba.
Est 4:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún. Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin.
Est 4:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Mordekai gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kun ara, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe sókè ó sì sọkún kíkorò. Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu-ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láààyè láti wọ ibẹ̀.