Est 4:1-17
Est 4:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati Mordekai mọ̀ gbogbo ohun ti a ṣe, Mordekai fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ-ọ̀fọ on ẽru bò ara, o si jade lọ si ãrin ilu na, o si sọkun kikan ati kikoro. O tilẹ wá siwaju ẹnu-ọna ile ọba: nitori kò si ẹnikan ti o fi aṣọ-ọfọ si ara ti o gbọdọ wọ̀ ẹnu-ọ̀na ile ọba. Ati ni gbogbo ìgberiko, nibiti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, ọ̀fọ nla ba gbogbo awọn Ju; ati ãwẹ, ati ẹkún, ati ipohùnrere; ọ̀pọlọpọ li o si dubulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ninu ẽru. Bẹ̃li awọn iranṣẹbinrin Esteri ati awọn ìwẹfa rẹ̀ wá, nwọn si sọ fun u. Nigbana ni inu ayaba bajẹ gidigidi; o si fi aṣọ ranṣẹ lati fi wọ̀ Mordekai, ati lati mu aṣọ-ọ̀fọ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ṣugbọn on kò gbà a. Nigbana ni Esteri pè Hataki, ọkan ninu awọn ìwẹfa ọba, ẹniti o ti yàn lati duro niwaju rẹ̀, o si rán a si Mordekai lati mọ̀ ohun ti o ṣe, ati nitori kini? Bẹ̃ni Hataki jade tọ̀ Mordekai lọ si ita ilu niwaju ẹnu-ọ̀na ile ọba. Mordekai si sọ ohun gbogbo ti o ri to fun u, ati ti iye owo fadaka ti Hamani ti ṣe ileri lati san si ile iṣura ọba, nitori awọn Ju, lati pa wọn run. Ati pẹlu, o fi iwe aṣẹ na pãpã, ti a pa ni Ṣuṣani lati pa awọn Ju run, le e lọwọ, lati fi hàn Esteri, ati lati sọ fun u, ati lati paṣẹ fun u ki on ki o wọle tọ̀ ọba lọ, lati bẹ̀bẹ lọwọ rẹ̀, ati lati bẹ̀bẹ niwaju rẹ̀, nitori awọn enia rẹ̀. Hataki si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ Mordekai fun Esteri. Esteri si tun sọ fun Hataki, o si rán a si Mordekai. Pe, gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ati awọn enia ìgberiko ọba li o mọ̀ pe, ẹnikẹni ibaṣe ọkunrin tabi obinrin, ti o ba tọ̀ ọba wá sinu àgbala ti inu, ti a kò ba pè, ofin rẹ̀ kan ni, ki a pa a, bikoṣe iru ẹniti ọba ba nà ọpá alade wura si, ki on ki o le yè: ṣugbọn a kò ti ipè mi lati wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ lati ìwọn ọgbọn ọjọ yi wá. Nwọn si sọ ọ̀rọ Esteri fun Mordekai. Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ. Nitori bi iwọ ba pa ẹnu rẹ mọ́ patapata li akokò yi, nigbana ni iranlọwọ ati igbala awọn Ju yio dide lati ibomiran wá; ṣugbọn iwọ ati ile baba rẹ li a o parun: tali o si mọ̀ bi nitori iru akokò bayi ni iwọ ṣe de ijọba? Nigbana ni Esteri rán wọn lọ ifi èsi yi fun Mordekai pe, Lọ, pè awọn Ju ti a le ri ni Ṣuṣani jọ, ki ẹnyin si ma gbãwẹ, fun mi, ki ẹnyin ki o máṣe jẹun, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ni ijọ mẹta t'ọsan t'oru: emi pẹlu ati awọn iranṣẹbinrin mi yio gbãwẹ bẹ̃ gẹgẹ; bẹ̃li emi o si wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ, ti o lòdi si ofin; bi mo ba ṣègbe, mo ṣègbe. Bẹ̃ni Mordekai ba ọ̀na rẹ̀ lọ, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Esteri ti paṣẹ fun u.

Est 4:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún. Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin. Ní gbogbo agbègbè ati káàkiri ibi tí òfin ati àṣẹ ọba dé, ni àwọn Juu tí ń ṣọ̀fọ̀ tí wọn ń gbààwẹ̀ tẹkúntẹkún. Ọpọlọpọ wọn da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n sì da eérú sára. Nígbà tí àwọn iranṣẹbinrin Ẹsita ati àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ sọ fún un nípa Modekai, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó kó aṣọ ranṣẹ sí i, kí ó lè pààrọ̀ àkísà rẹ̀, ṣugbọn Modekai kọ̀ wọ́n. Ẹsita bá pe Hataki, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí ọba ti yàn láti máa ṣe iranṣẹ fún un. Ó pàṣẹ fún un pé kí ó lọ bá Modekai kí ó bèèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó fà á. Hataki lọ bá Modekai ní ìta gbangba, níwájú ẹnu ọ̀nà ààfin ọba. Modekai sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, títí kan iye owó tí Hamani ti pinnu láti gbé kalẹ̀ sí ilé ìṣúra ọba kí wọ́n fi pa àwọn Juu run. Modekai fún Hataki ní ìwé òfin tí wọ́n ṣe ní Susa láti pa gbogbo àwọn Juu run patapata, pé kí ó fi ìwé náà han Ẹsita, kí ó sì là á yé e, kí ó lè lọ siwaju ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀. Hataki pada lọ ròyìn ohun tí Modekai sọ fún Ẹsita. Ẹsita tún rán an pada sí Modekai pé, “Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ati gbogbo eniyan ni wọ́n mọ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá lọ sọ́dọ̀ ọba ninu yàrá inú lọ́hùn-ún, láìṣe pé ọba pè é, òfin kan tí ọba ní fún irú eniyan bẹ́ẹ̀ ni pé kí á pa á, àfi bí ọba bá na ọ̀pá wúrà tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni náà ni wọn kò fi ní pa á. Ṣugbọn ó ti tó ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn tí ọba ti pè mí.” Nígbà tí Modekai gbọ́ ìdáhùn yìí láti ọ̀dọ̀ Ẹsita, ó tún ranṣẹ sí Ẹsita pada, ó ní, “Má rò pé ìwọ nìkan óo là láàrin àwọn Juu, nítorí pé o wà ní ààfin ọba. Bí o bá dákẹ́ ní irú àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́, ati ìgbàlà yóo ti ibòmíràn wá fún àwọn Juu, ṣugbọn a óo pa ìwọ ati àwọn ará ilé baba rẹ run. Ta ni ó sì lè sọ, bóyá nítorí irú àkókò yìí ni o fi di ayaba?” Ẹsita bá ranṣẹ sí Modekai, ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa jọ, kí ẹ gba ààwẹ̀ fún mi fún ọjọ́ mẹta, láìjẹ, láìmu, láàárọ̀ ati lálẹ́. Èmi ati àwọn iranṣẹ mi náà yóo máa gbààwẹ̀ níhìn-ín. Lẹ́yìn náà, n óo lọ rí ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin, bí n óo bá kú, kí n kú.” Modekai bá lọ, ó ṣe bí Ẹsita ti pàṣẹ fún un.
Est 4:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Mordekai gbọ́ gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì fi eérú kun ara, ó jáde lọ sí inú ìlú ó kígbe sókè ó sì sọkún kíkorò. Ṣùgbọ́n ó lọ sí ẹnu-ọ̀nà ọba nìkan, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀ tì a gbà láààyè láti wọ ibẹ̀. Ní gbogbo ìgbèríko tí àṣẹ ikú ọba dé, ọ̀fọ̀ ńlá dé bá àwọn Júù, pẹ̀lú àwẹ̀, ẹkún àti ìpohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nínú aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi eérú kúnra. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìwẹ̀fà Esteri wá, wọ́n sọ nípa Mordekai fún un, ayaba sì wà nínú ìbànújẹ́ ńlá. Ó fi aṣọ ránṣẹ́ sí i kí ó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀ tí ó wọ̀, ṣùgbọ́n òun kò gbà wọ́n. Nígbà náà ni Esteri pe Hataki, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Mordekai àti ohun tí ó ṣe é. Bẹ́ẹ̀ ni Hataki jáde lọ bá Mordekai ní ìta gbangba ìlú níwájú ẹnu-ọ̀nà ọba. Mordekai sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hamani ti ṣe ìpinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù. Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun wọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Susa, láti fihan Esteri kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún un, ó sì sọ fún un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ síwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀. Hataki padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Esteri ohun tí Mordekai sọ. Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai, “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.” Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai, Nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé; “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù. Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?” Nígbà náà ni Esteri rán iṣẹ́ yìí sí Mordekai: “Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Susa jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi. Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin. Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé.” Bẹ́ẹ̀ ni Mordekai lọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí Esteri pàṣẹ fún un.